Mo fẹẹ fi ayẹyẹ ọjọọbi mi dupẹ lọwọ Ọlọrun- Sẹnetọ Iyabọ Aniṣulowo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 15 March 2026

Mo fẹẹ fi ayẹyẹ ọjọọbi mi dupẹ lọwọ Ọlọrun- Sẹnetọ Iyabọ Aniṣulowo

Sẹnetọ Iyabọ Aniṣulowo, ẹni to ti figba kan ọmọ ile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja, fun ẹkun Ogun West, ti sọ pe ayẹyẹ ọjọọbi karundinlọgọrin, toun fẹẹ ṣe wa fun lati fi dupẹ lọwọ Ọlọrun.

O sọrọ yii nibi ipade oniroyin to waye, o sọ pe gbogbo eto lo ti to fun ayẹyẹ ọjọọbi ọhun ti yoo waye lọjọ Abamẹta,Satide, ọsẹ yii tii ṣe ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹta, ọdun yii niluu Ilaro.

O ṣalaye siwaju pe oun mọ ọn mọ fẹẹ fi ọjọọbi ọhun fi ẹmi imoore han si Ọlọrun,nitori oore rẹ lori oun.

Ẹni to ti figba kan jẹ minisita feto ẹkọ tun ṣalaye pe awọn tun fẹẹ lo ọjọọbi ọhun lati fi ṣe iranti awọn nnkan to ti ṣẹlẹ to si yẹ ki oun maa gbegbe ọpẹ.

O ni " Mo ranti ni nnkan bi ọdun mẹwaa sẹyin ti ko pẹ ti mo ṣọjọọbii lawọn kan ji mi gbe, ti Ọlọrun ko mi yọ".

Bẹẹ lọdun 2020, tawọn tun fẹẹ ṣayẹyẹ ọjọọbi,korona ko jẹ kawọn ṣe bi wọn ṣe fẹẹ, nitori asiko ọhun lawọn eeyan ma faṣọ bomu, awọn kan ṣe ranpẹ niluu Abuja.

Amọ ti tọjọ Satide to n bọ yii ko ri bẹẹ, nitori pe bawọn ba ṣe n pari isin idupẹ gbọngan ibi ti wọn yoo ti ṣefilọlẹ iwe to n kọ lati fi ṣaami ọjọ naa lawọn n lọ.

Iyabọ Aniṣulowo tun ṣalaye pe ọrọ oun to ọpẹ, o tun juu lọ fawọn iriri toun ti ni ko to di pe oun ṣe oṣelu, paapaa julọ nipa eto ẹkọ, ti wọn ti fiṣẹ olukọni bẹrẹ.

O ni, " Mo dupẹ fun oore ọfẹ ti mo ri gba latilẹ wa, nitori idi eyi ni mo ṣe fiwe pe awọn oloṣelu, ki wọn wa rọgba yi mi ka lọjọ naa lati ba mi ṣe ajọyọ.
"Ootẹli Yewa Frontier to wa ni Ilaro lati ma ṣe ikojade iwe tuntun ti mo ṣẹṣẹ kọ, eyi to sọ nipa itan igbesi aye atawọn iriri mi ninu aye to fi mọ oṣelu"


No comments:

Post a Comment

Pages