Bẹẹ wọn ni Dapọ Abiọdun ni olori ẹgbẹ APC ni Ogun
Bi ọjọ meloo kan lawọn kanselọ kan ko ara wọn jọ ti wọn pariwo sita pe awọn dide lati ṣatilẹyin fun Sẹnetọ Ọlamilekan Solomon Adeọla, tọpọ mọ si Yayi lati dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun.
Ṣugbọn ọrọ ti bẹyin yọ bayii nitori bawọn kanselọ kan ṣe sọ pe awọn ko mọ nnkankan nipa ẹ ati pe apo ara wọn lawọn yẹn sọ si.
Nibi ipade oniroyin tawọn kanselọ naa ṣe lonii lawọn kanselọ marundinlogoji lati Ogun West labẹ ẹgbẹ wọn to jẹ ti Dapọ Abiọdun ni wọn ti sọ pe irọ to jinna sootọ ni pe kanselọ mọkandinlọgọta to wa ni Ogun West fọwọ si Yayi.
Ninu ọrọ Ọnarebu Lateef Oseni, igbakeji adari awọn kanselọ nijọba ibile Ado- Odo- Ọta, lo ti sọ pe ko si adehun kankan laarin awọn kanselọ lati jumọ fa ẹnikan kalẹ ni Ogun West fun ipo gomina.
O waa kilọ fawọn agba ẹgbẹ oṣelu lagbegbe ọhun ki wọn yẹra lati fa ẹni ti ko nimọ kikun nipa agbegbe Ogun West kalẹ.
O sọ pe ẹni tawọn n fẹ lati dije gomina lẹni to mọ nipa gbongbo, to sunmọ araalu, to si tun jẹ ojulowo ọmọ ilu.
Ọnarebu Oseni ṣalaye siwaju pe Ogun West ti kọja ẹni ti wọn le maa ti gbọn-gbọn-gbọn,nitori Ọlọrun fawọn to ni iriri,ọgbọn ati imọ oṣelu jinki wọn, ko waa yẹ kawọn kan wa maa sọ pe awọn ti panupọ lati fa oludije kalẹ, ọrọ buruku gba a lo pe e.
O sọ pe " Titi di akoko yii gbogbo ẹnu ni mo fi sọ ọ pe ko sigba kankan ti awa kanselọ ni Ogun West fẹnuko pe ki a fun ẹnikan laaye lati dije fun ipo gomina"
Bakan naa lawọn kanselọ yii tun fi atilẹyin wọn han si ẹgbẹ APC, fun ibo aarẹ to n bọ lọdun 2027.
Bẹẹ ni wọn tun gboriyin fun Gomina Dapọ Abiọdun fun ọpọlọ ti Ọlọrun fun un eyi to fi n dari ipinlẹ Ogun,
Ọnarebu Oseni sọ pe aṣaaju rere ni tawọn si n fi ṣe awokọṣe, o waa fi akoko naa rọ awọn Ẹgba ati Ijẹbu ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu wọn lati jẹ ki ipo gomina wa lati Ogun West.
No comments:
Post a Comment