Ṣe lawọn araalu to wa nibẹ bẹrẹ si nii bẹ Salvador lati jade dupo gomina nibi iboto n bọ lọdun 2027.
Gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe wi lọjọ naa wọn ni ipa kekere kọ ni ọkunrin naa ninu idagbasoke ipinlẹ Eko.
At pe ẹlẹyinju aanu ni wọn tun pw, ti wọ lo n ṣe fun onikaluku laifi ti ọrọ ẹyin tabi ẹlẹyamẹyaṣe.
Ọkan lara awọn eeyan ọhu Saburi Ayọmikun, o sọ pe ọmọ bibi ipinlẹ Eko loun ati pe ohun ti mọ Ọnarebu Savador lati nnkan bi ọgbọn ọdun sẹyin ati pe ọpọ anfaani loun ti jẹ lọdọ rẹ.
O ni eeyan ti Ọlọrun fi ọpọlọ jinki ẹ ni,to si le fi dari ipinlẹ Eko lọna ti yoo mu eṣo rere jade, o waa rọ Salvador lati gbe ọrọ naa yẹwo.
Ninu ọrọ Arabinrin Chioma Matthew, o ṣapejuwe Ọnarebu Salvador gẹgẹ bi ẹni to tun le mu atubọtan ba ipinlẹ Eko,ti wọn ba le fun ni tikẹẹti oludije, o ni gbogbo awọn to jẹ ibo nipinlẹ Eko lawọn yoo tii lẹyin, nitori ọrẹ mẹkunnu ni.
Ninu ọrọ Ọnarebu Adegoke Salvador, o sọ
pe ọkan lara iṣẹ to yẹ ki adari ilu maa ṣe loun ṣe yẹn toun yoo si tubọ lati maa ṣe e.
O ṣapejuwe adari gẹgẹ iru eeyan too jẹ ati nnkan too ni.Koda, o ni iwe kuraani jẹri si pẹlu.
Adegoke tun ṣalaye siwaju pe idi niyii toun fi maa n fi isọkan ṣe akori. O ni nnkan to tun da wahala silẹ ni aṣilo agbara tawọn adari n lo ti wọn ba ti wa nipo.
O fi ti Doland Trump aarẹ orileede Amẹrika ṣe apẹẹrẹ lori aṣiio agbara, eyi to mu kawọn ọrẹ ẹ di ọta ẹ.
Lori bawọn eeyan ṣe n pariwo lọjọ naa pe ko jade dupo gomina, o sọ pe nnkan to gba ero lati ro daadaa ni. O ni yala ki oun jade tabi ki wọn foun ni ọdọ toun yoo fi imọ ati oye tọ
Lara nnkan ti wọn pin fawọn eeyan lọjọ naa ni ounjẹ loriṣiriṣi ati aṣọ.
No comments:
Post a Comment