Bo tilẹ jẹ oriṣii ahesọ lo ti n lọ nigboro pẹ ẹnikan ṣoṣo ni Yewa fẹẹ fa kalẹ lati dije tawọn kan si sọ pe Sẹnetọ Ọlamilekan Adeọla tọpọ mọ si Yayi ni, nitori bi wọn ṣe n fojoojumọ polongo ẹ gẹgẹ bi oludije.
Ṣugbọn ni bayii, Ọnarebu Gboyega Nasir Isiaka tọpọ mọ si GNI, ti waa sọ pe bo tilẹ jẹ pe ẹnikan ṣoṣo ni Yewa yoo fa kalẹ labẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun, oun ni ẹni naa, oun si ti ni igbaradi bayii lati dije.
Awọn to sunmọ GNI, sọ fun wa pe ariwo kọ ni oṣelu bi ko ṣe ẹni tawọn araalu ba dibo yan ati pe ti Yayi ki i ṣe akọkọ, awọn kan naa ti pariwo lakooko oṣelu, to jẹ pe pabo ni gbogbo rẹ ja si.
Iwadii fi ye wa pe kaakiri ipinlẹ Ogun lawọn araalu ti n fifẹ wọn han si GNI lati jade dupo, ti wọn si n daṣa pe oun lokan, wọn ṣetan lati gbe e fun.
Iyẹn nikan, a tun gbọ pe ninu ijọba ta a n lo lọọ yii atilẹyin ti wọn fun un ki i ṣe kekere ti wọn si n fi lọkan balẹ pe tikẹẹti gomina ibo 2027, yoo tẹ lọwọ, ti yoo si de ipo naa.
Bo tilẹ jẹ pe igba akọkọ kọ ree, ti Ọkunrin to jẹ ọmọ Imẹkọ Afọn yii yoo jade dupo gomina, amọ ti ko bọ si, idi niyii tawọn ara ipinlẹ Ogun ṣe n sọ pe ti gbaradi fun.
Ohun tawọn kan tun sọ ni pe GNI jẹ ẹni tawọn mọ ibi to ti jade wa ti wọn le tọpinpin iran wọn titi di akoko yii, o yatọ sawọn kan ti oṣelu sọ wọn di ọmọ ilu tipatipa.
Ju gbogbo ẹ lọ, ariwo GNI lo n gba ode kan eyi to mu idaamu bawọn kan.
No comments:
Post a Comment