Ọwọ aṣọbode tẹ fayawọ to fẹẹ gbe àkàlà wọlu - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 14 February 2026

Ọwọ aṣọbode tẹ fayawọ to fẹẹ gbe àkàlà wọlu

Lọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ ta a lo tan yin lawọn aṣọbode tẹ ọkunrin kan to  fayawọ akala to wa ninu pẹpẹ, to fẹẹ ko wọlu, lọns Yemoata,Abule- Igboora,Ebute Igboora,lọna Idi iroko, ipinlẹ Ogun.

Gẹgẹ bi Zakari Chado, agbẹnusọ fawọn aṣọbode nipinlẹ Ogun ṣe wi, o ni ọlọkada kan lo ṣadeede ko awọn akala naa bọ latinu igbo.

O ni bo ṣe rawọn aṣọbode ọhun lo gbe ọkada ẹ silẹ to ṣalọ, ti wọn ko si tii ri titi di akoko yii.

O ṣalaye ṣiwaju pe loju ẹṣẹ ni ọkan lara awọn ọga aṣọbode, Ọgbẹni Tajudeen Bello, ti fa akala ti wọn ri gba le wọn lọwọ nileeṣẹ ni ọgba awọn ẹranko lorukọ ọga agba wọn iyẹn Ọladapọ Afẹni.

Afẹni waa gboriyin fun awọn oṣiṣẹ ẹ fawọn iṣẹ akọni ti wọn n ṣe bẹẹ lo tun rọ wọn lati ma ṣe rẹwẹsi nipa idojukọ awọn fayawọ ki wọn ba le dinku lawujọ.

Bakan naa lo fi akoko naa kilọ fawọn ti wọn wọnu ọgba ẹranko lati maa ṣe fayawọ pe ki wọn jawọ, ki wọn ma ba a faṣọ penpe roko ọba.

No comments:

Post a Comment

Pages