Ọjọgbọn Arigbabu, Oloye Fanimokun, Alaaja Sinat Ojikutu atawọn yooku ṣatilẹyin ẹdawo fun ileewe kọlẹẹji Yewa Ẹgbado,Ilaro - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 7 February 2026

Ọjọgbọn Arigbabu, Oloye Fanimokun, Alaaja Sinat Ojikutu atawọn yooku ṣatilẹyin ẹdawo fun ileewe kọlẹẹji Yewa Ẹgbado,Ilaro

Ọjọgbọn Abayọmi Arigbabu, kọmiṣanna feto ẹkọ ati imọ igbalode nipinlẹ Ogun, ti rọ gbogbo awọn to jade nileewe kọlẹẹji Yewa Ẹgbado, to wa niluu Ilaro lati dide iranlọwọ fun ileewe ọhun ki idagbasoke tubọ le ma ba a.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Ọgbẹni Kẹhinde Ṣoaga, ọkan lara igbimọ fun iroyin fi sita lo ti ṣalaye pe ọdun 1951 ni wọn da ileewe ti wọn pe ni Ẹgbado College yii silẹ niluu Ilaro, ki wọn to yi orukọ ẹ pada si ileewe kọlẹẹji Yewa, ti wọn ṣayẹyẹ ọdun karundinlọgọrin ti wọn da a silẹ.

Ayẹyẹ ọhun to waye ni Eko Hotel, lọjọ kẹrin, oṣu yii lawọn ti wọn jade nileewe ọhun ti wọn ti di ẹni pataki, ti wọn si ti dipo nla mu lawujọ ti peju pesẹ.

Lara wọn ni Ọjọgbọn Abayọmi Arigbabu, kọmiṣanna feto ẹkọ nipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Iyabọ Aniṣulowo, Alaaja Ṣinat Ojikutu, to ti figba kan jẹ igbakeji gomina nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Rahman Bello,ọga agba tẹlẹ nileewe giga yunifasiti Eko, Kaputeeni Adewale Iṣọla atawọn eeyan jakanjakan mii-ii.

Nibi ayẹyẹ ọhun ni Oloye Iyabọ Apampa ti fi adura bẹrẹ, bẹẹ lọrọ iṣiti loriṣiriṣii tun waye latọdọ awọn ti wọn wa nibẹ.

Pabanbari ẹ ni ẹdawo oni biliọnu lọna ogun naira to waye fun idagbasoke ileewe ọhun lati le jẹ ko ba tode onii mu, eyi ti Aarẹ ẹgbẹ awọn to jade nileewe naa,Ọmọọba Dasaolu Ọlaniyi Ọladimeji atawọn oloye ẹ dawọ le.

Ọsẹ kan ni wọn ti ya sọtọ, eyi to ti bẹrẹ lọjọ kẹrin oṣu yii fun ayẹyẹ ọdun karundinlọgọrin ti wọn da ileewe naa silẹ pẹlu ẹdawo ti yoo si wa sopin lọjọ kẹẹẹdogun oṣu yii.

No comments:

Post a Comment

Pages