Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ẹṣọ aṣọbode,Chado Zakari fi sita,o ni lakooko ti ọga agba ọhun lọọ sabẹwo ki ni aafin ẹ, lọjọ kẹta, oṣu yii, lo sọrọ naa.
O gboriyin fun ẹṣọ aṣọbọde fawọn ipa takubtakun ti wọn ti ko sẹyin lati le dẹkun awọn onifayawọ ti wọn ṣakoba fọrọ aje wa.
Ọba Ọlaniyan wa kii Afẹni to ṣspejuwe gẹgẹ bi ọmọ onilẹ pẹlu ileri pe gbogbo atilẹyin ti wọn ba fẹẹ loun atawọn araalu Ipokia yoo maa ṣe fun.
Ko to to akoko naa ni Ọga agba aṣọbode nipinlẹ Ogun, Ọladapọ Afẹni lo ti dupẹ lọwọ ọba alaye ọhun fun igbalejo wọn.
O ṣapejuwe ilu Ipokia gẹgẹ bi eyi to ko awọn eeyan mọra ti alaafia si jọba nibẹ. O waa ṣalaye idi pataki to fi ṣabẹwọ sọdọ ọba atawọn oloye ẹ lati jọ fimọ sọkan lori bi wọn ṣe le gbogun tawọn onifayawọ.
O mẹnuba awọn aleebu tawọn onifayawọ ti mu ba ilẹ wa ati akude ti wọn mu ba ọrọ aje wa lapapọ.
No comments:
Post a Comment