Nitori idagbasoke to ti mu ba ilu Keesi:Wọn fi Ṣẹgun Ṣowunmi joye Ọdọfin - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 19 February 2026

Nitori idagbasoke to ti mu ba ilu Keesi:Wọn fi Ṣẹgun Ṣowunmi joye Ọdọfin

Idunnu ṣubu layọ lọjọọru, Wẹsidee, nigba ti wọn fi agba oṣelu nni Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi joye Ọdọfin gbogbo Keesi, eyi to waye nile Ogboni Keesi, niluu Abẹokuta nibi tawọn eeyan jakanjakan ti peju pesẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọkan lara oye ilu pataki ni Ọdọfin, to si jẹ pe wọn ko le fi eeyan yẹpẹrẹ jẹ lawujọ.

Ki i ṣe pe wọn mọ ọn mọ fi ẹni to jẹ oludasilẹ ẹgbẹ kan to n wa ọna abayọri si oṣelu iyẹn 'The Alternative' joye tuntun ọhun bi ko ṣe awọn ipa to ti ko fun idagbasoke awujọ nipasẹ ọrọ aje ati niluu Keesi funra ẹ.

Ninu ọrọ Ọdọfin tuntun naa lẹyin ti wọn fa ọwọ ẹ soke lo ti ṣalaye pe Keesi jẹ ọkan lara ọmọ mẹrin ti wọn wa.

O ni Keesi ni ẹgbọn nigba ti Kemta tẹle, Ketu to wa ni orileede Benin ati Ake to jẹ aburo gbogbo wọn.

O ṣalaye siwaju pe" Ni Keesi wa nibi, Oluwo ni olori gbogbo wọn, lẹyin naa lo kan Ọdọfin, koda oye idile Akinrogun ti mo ti wa lo n jẹ.

Baba to bi baba mi ni Ọdọfin, baba mi ni Balogun to wa nibẹ bayii, nigba ti ẹgbọn mi si jẹ Apena, gbogbo awọn eeyan yii lo si ti n di arugbo lọ".

O ni asiko si ti to fun awọn to jẹ ọmọ wọn lati kopa ninu ọrọ ilu ko ma ba a parun. O lawọn nnkan to lapẹẹrẹ ni rere lo ti waye niluu naa.

Lara ẹ ni ọsibitu, ileewe ati gbọngan akọkọ bẹẹ naa lo sọ pe ile ogboni wọn lakọkọ to si tun tobi ju nilẹ Ẹgba.

O waa ni gbogbo ọna ati ipa lawọn yoo sa lati ṣawaari gbogbo ọmọ Keesi lọkunrin ati lobinrin, ki wọn le lọwọ ninu idagbasoke ilu.

No comments:

Post a Comment

Pages