Ijẹbu-Ode yoo gbalejo ipade nla ti ẹgbẹ alatilẹyin Yayi iyẹn 'Ogun Visionaries' fẹẹ ṣe lọjọ Tọsidee, ọsẹ yii. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday, 9 February 2026

Ijẹbu-Ode yoo gbalejo ipade nla ti ẹgbẹ alatilẹyin Yayi iyẹn 'Ogun Visionaries' fẹẹ ṣe lọjọ Tọsidee, ọsẹ yii.

Ni bayii gbogbo eto lo ti to fun ipade gbọngan nla ẹlẹẹkeji iru ẹ, eyi ti ẹgbẹ to n ṣatilẹyin fun Yayi, iyẹn Ogun Visionarries, sagbatẹru ẹ, ti yoo waye ni Tọsidee, ọjọ kejila, oṣu keji ọdun yii ni gbọngan RONTEX, to wa nidojukọ Old Burial Ground, lọna Ibadan, niluu Ijẹbu Ode.Aago mọkanla geere ni wọn yoo bẹrẹ.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Ọnarebu Monsuru, alaga igbimọ eto ọhun fi sita lo ti sọ pe awọn ti wa ni igbaradi ati pe ohun ti ipade naa duro lori ni lati jọ fikunlukun ọna ti wọn le gba ṣatilẹyin fun Sẹnetọ Ọlamilekan Yayi, lati le di gomina fọdun 2027.

O ṣalaye pe ọpọ awọn eeyan jakanjakan lawọn ti fiwe pe lati wa ba awọn eeyan sọrọ nibi ipade naa.

Ati pe Dokita Isiaq Adekunle Salakọ, to jẹ minisita fun eto ilera lorileede yii ni alaga ọkunrin lọjọ naa, nigba ti Dokita Oluwakemi Binta Shoge, si jẹ alaga obinrin.

Iya ọjọ naa ni Ọtunba Dokita Aderonkẹ Kọlade Cairo, Ẹẹta Iyalode Bọbakẹyẹ Obinrin Akilẹ ati iya isalẹ Ogun  Visionaries.

Olori ile igbimọ aṣofin tẹlẹ, nipinlẹ Ogun Tunji Ẹgbẹtokun,  yoo bawọn eeyan sọrọ lọjọ naa pẹlu  Ọnarebu Ọnadẹkọ Ọnanusi.

Awọn ọba alaye ti wọn tun reti lọjọ naa ni
Ọba Adedọtun Pdunneye Odusanya, JP, Oṣijiya II, Olu of Odonṣelu, Alarọ Kingdom, Ijẹbu ati Ọba Kazeem Adesina Salami, Ilufẹmilọba I, Osobia ,Makun-Omi.

Awọn ti wọn yoo tun fikunlukun pẹlu awọn araalu lọjọ naa ni Dokita Niyi Ọṣọba ati Oloye  Ṣẹgun Ojolowo Ojuko
to jẹ Ogboye Ota nilẹ Awori, Ọnarebu
Tọla Banjọ, Olootu Bọlaji Adeniji, ati Princess Florence Feyikemi.

Nigba ti Oloye Ajirọba Dapọ Ọkẹ, lati ileewe yunifasiti olukọni Tai Solarin, Ijagun,  yoo ṣagbeyẹwo lọjọ naa

Alakoso agba fun Ogun Visionaries for Yayi, Ọdunlẹyẹ Ọdunjo, ni yoo gba awọn eeyan lalejo

No comments:

Post a Comment

Pages