Lọjọọru, Wẹsidee, to kọja yii niroyin gba igboro pe ẹni to ti figba kan jẹ igbakeji ọga agba banki ilẹ wa iyẹn CBN, Ọmọwe Tunde Lẹmọ, ti jade tan sita, to si loun ti ṣetan lati dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ninu ibo ọdun 2027.
Ko to to akoko yii la ti gbọ pe awọn kan naa lati aarin gbungbun,iyẹn Ogun Central, ti n kede pe awọn naa fẹẹ dupo gomina latilẹ Ẹgba. Awọn naa ni Ambasedọ Ṣarafa Iṣọla, Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ, Dimeji Bsnkọle, Ọnarebu Kayọde Amuṣan atawọn kan ti wọn ko tii gbe ipinnu wọn jade.
Ninu gbogbo awọn ta a darukọ yii ko si eyi ti wọn sọ pe o mu ibẹrubojo ba a to si n roo pe irọrun ni tikẹẹti naa yoo jẹ foun.
Iyẹn nikan kọ, ni Ogun West ti Yayi loun ti fẹẹ jade lawọn bii Ọnarebu Gboyega Nasir, Ọnarebu Abiọdun Akilade ati Ọnarebu Hunyẹ ti wọn jọ wa ninu APC naa ti sọ fun Yayi pe fada keresi ni gbogbo eyi to n ṣe kaakiri ipinlẹ Ogun, awọn yoo jọ na tan bi owo ni.
Ṣugbọn lọsẹ to kọja ti Tunde Lẹmọ jade gẹgẹ bi ondupo ni wọn sọ pe jẹbẹtẹ ti gbọmọ le Yayi lọwọ.
Idi abajọ si ni pe ariwo tawọn Ẹgba n pa ni pe awọn nipo gomina kan lọdun 2027, niwọngba ti Ijẹbu Rẹmọ ṣẹṣẹ n pari ọdun mẹjọ wọn lọ.
A o si ranti pe nigba ti ariwo Ẹgba lokan n gbilẹ ni Yayi bọ sita pe ọmọ Ẹgba loun naa, nitori ọmọ Kemta ni iya to bi oun lọmọ, eeyan ko si n nile baba, ko maa nile iya.
Ṣugbọn awọn tọrọ oṣelu ye sọ pe ti ọrọ ba doju ẹ, awọn to jẹ ojulowo ọmọ Ẹgba yoo yọju tawọn eeyan yoo si foju ara wọn ri.
Iwadii si fi ye wa pe gbọingbọin lawọn ọmọ Ẹgba ati Ijẹbu duro lẹyinTunde Lẹmọ, igbakeji gomina banki ilẹ wa, ti wọn si n sọ pe awọn ṣetan lati tii lẹyin.
Ohun tawọn kan tiẹ n sọ ni pe asiko ti fẹẹ to ti onikaluku yoo fi oju oori baba ẹ han lati mọ ojulowo ọmọ.
Gbogbo nnkan wọnyii ni wọn sọ pe o kọ Yayi atawọn eeyan lominu ti wọn fi ni ẹrin wọn akoko yii ko denu.Lemọ lawọn eeyan foju sọna fun un.
No comments:
Post a Comment