Ẹgbẹ AA yan Ṣowunmi fun ipo oludije sipo Gomina ti yoo ko wọn de Oke-Mọsan lọdun 2027 - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 28 February 2026

Ẹgbẹ AA yan Ṣowunmi fun ipo oludije sipo Gomina ti yoo ko wọn de Oke-Mọsan lọdun 2027

Lana-an, ode oni yii ẹgbẹ oṣelu Action Alliance, AA, waa ṣe ipade pọ pẹlu Ọdọfin tiluu Kemta Ẹgba, Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi lati wa dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu wọn fun ibo 2027.

Ninu ọrọ Ọjọgbọn Tunde Adebọla to jẹ alaga ẹgbẹ naa lo ti fi idunnu wọn han sawọn ipa ti ẹni to da ẹgbẹ ọna abayọ iyẹn The Alternative silẹ ti ko fun idagbsoke ipinlẹ Ogun.

O ni iru awọn eeyan bi tiẹ lawọn araalu n fẹ lati ṣe adari nipinlẹ Ogun, idi niyii tawọn ṣe fẹẹ ko dari ẹgbẹ wọn lọọ si Oke- Mọsan lọdun 2027.

Ninu ọrọ Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, lo ti dupẹ lọwọ wọn fun erongba rere ti wọn ni lọkan foun.

Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi ti waa rọ awọn to fẹẹ jade dupo gomina fọdun 2027, nipinlẹ Ogun lati yẹra fun oṣelu ẹtanu, kaka bẹẹ ki wọn jẹ kawọn araalu mọ nipa nnkan ti wọn ni fun wọn.

Lọjọ Ẹti, lo sọrọ ọhun lakooko ti ẹgbẹ oṣelu kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Action Alliamce, AA, ṣabẹwo lọ sọdọ ẹ lati jẹ ko darapọ mọ wọn, ko si jade dupo gomina fun ipo gomina.

Ọkunrin naa fi aidunnu ẹ han lori bawọn oludije gomina kan ṣe n fẹnu tẹnbẹlu akẹgbẹ ẹ ti wọn fẹẹ jọ jade dupo yii, o ni eyi ko dara to kaka bẹẹ ki wọn sọ ọna ti wọn fi le mu idagbasoke ba ilu.

Ọtunba Ṣowunmi tun fikun ọrọ ẹ pe awọn ọmọ ipinlẹ Ogun ti kọja ẹni ti wọn le maa fi ọrọ ẹlẹyamẹya tan jẹ bi ko ṣe oludije to ṣetan lati ṣariyanjiyan to doju ẹ lori ọrọ aje ati idagbasoke ilu fun wọn.

O sọ pe " Loju temi oludije ti ko ba le sọ pato nnkan to ni fawọn araalu, to fi ọtẹ silẹ, to n pa lapalapa, bawo ni ẹ ṣe fẹẹ ka ṣiṣẹ fun onitọhun, bawo la ṣe fẹẹ ni igbẹkẹle ninu onitọhun.

" Ẹ jẹ kawọn oludije dupo gomina jade sita, ki wọn jẹ kawọn araalu mọ ohun ti wọn ni ati idi ẹ"

Bẹẹ ni oludasilẹ ẹgbẹ to n wa ọna abayọ yii tun rọ awọn oloṣelu ti wọn nigbagbọ ninu fifi owo dibo, o ni eleyii ki i jẹ ki eto oṣelu wa ri bi a ṣe n fẹ.

Lori bi ẹgbẹ oṣelu AA ṣe ni ko waa jade dupo gomina fọdun 2027, Ṣowunmi sọ pe ara ilọsiwaju ninu oṣelu ni.

Ati pe awọn ẹgbẹ oṣelu bii Labour Party, NDP, ADP,naa ti wa fun iru erongba yii, ti wọn si n lawọn n fẹ ki n jẹ aṣaaju wọn.

O ni gẹgẹ bi wọn ṣe mọ oun ṣi ni ẹni to pẹ ju ninu ẹgbẹ oṣelu PDP titi di akoko yii, toun ko si ti i kuro nibẹ.

O ni o fẹẹ jẹ pe ko si ẹgbẹ oṣelu alatako kan ti ko nii wahala ti wọn ko tii gbe ara wọn lọ sile ẹjọ.

Ṣowumi tun ṣalaye pe" Gẹgẹ bi mo ṣe gbọ,ẹgbẹ oṣelu APC nikan ni wọn ko gbe iru igbesẹ bẹẹ, bigba ta a ba n fi ara wa ṣe ẹlẹya oṣelu dẹmokiresi ti ko si yẹ ko ri bẹ.

No comments:

Post a Comment

Pages