APC ipinlẹ Ogun gboriyin lori ipade gbogbogboo ti wọọdu to waye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 18 February 2026

APC ipinlẹ Ogun gboriyin lori ipade gbogbogboo ti wọọdu to waye

Ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ogun ti gboriyin fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ ọhun lori bi ipade gbogbogboo to waye lawọn wọọdu ṣe waye nirọwọ-rọsẹ ti ko si wahala nibikibi.

Ninu atẹjade kan ti Ọnarebu Fẹmi Nuberu, to jẹ akọwe olupolongo ẹgbẹ naa fi sita l'Ọjọọru, Wẹsidee, lo ti ṣalaye pe eto ọhun to waye yii nibi tawọn ojulowo ọmọ ẹgbẹ ti kopa ṣafihan iṣọkan ati ifẹ to wa laarin gbogbo wọn.

O fikun ọrọ ẹ pe bi wọn ṣe ṣagbekalẹ ẹ tun jẹ itẹwọgba gbogbọ ọmọ ni ilana ati ofin ti wọn la kalẹ fun wọn, eyi to jẹ ko so eso rere.

Ọnarebu Nuberu tun tẹsiwaju ninu atẹjade naa pe awọn fi idunnu awọn han sawọn agba ẹgbẹ lapapọ lori bi wọn ṣe pese awọn ilana to tọ to si yẹ lati jẹ ko so eṣo rere.

Bẹẹ ni wọn tun dupẹ lọwọ awọn igbimọ kọọkan, awọn eleto aabo, awọn to ṣeto idibo,awọn oloye ẹgbẹ lawọn ijọba ibilẹ, fawọn ipa ti wọn ko fun aeyọri nla naa.

O ni abajade ipade gbogbogboo ọhun to waye yii tun jẹ ki igbẹkẹle wa lori awọn adari wọn fun ilakaka wọn fun itankalẹ kaakiri awọn igberiko.

O waa lo akoko naa lati ki awọn ti wọn ṣẹṣẹ yan jakejado wọọdu ku oriire, pẹlu rirọ wọn lati ṣojuṣe ipo ti wọn yan wọn si, ki wọn ṣi ṣee tọkantọkan.
 
O ni ẹgbẹ oṣelu APC Ogun ṣi wa niṣọkan ti wọn si n ri daju pe wọn tẹsiwaju lati rii pe iṣejọba yii rọ gbogbo mutumuwa lọrun.

No comments:

Post a Comment

Pages