Aarẹ Tinubu gboṣuba fun ileewe FUNAAB fawọn ipa wọn lori idagbasoke lorileede yii. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 1 February 2026

Aarẹ Tinubu gboṣuba fun ileewe FUNAAB fawọn ipa wọn lori idagbasoke lorileede yii.

Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ti gbe oṣuba o kaare fun ileewe giga yunifasiti imọ ọgbin to wa niluu Abẹokuta iyẹn FUNAAB fawọn ipa pataki ti wọn ti ko lorileede yii fun idagbasoke ti wọn ti mu ba agbaye ati orileede yii nipasẹ ipese aabo ounjẹ lawujọ.

O gboriyin yii nibi ayẹyẹ ikẹkọọjade ẹlẹẹkẹtalelọgbọn ileewe ọhun to waye niluu Abẹokuta, nibi tawọn to le ni ẹgbẹrun mẹrin ti kawe gboye lawọn ẹka kọọkan ileewe naa.

Ninu ọrọ ẹ to fi ran  akọwe agba nijọba apapọ fun ileeṣẹ to n ri si ọrọ ọgbin ati aabo ounjẹ lorileede yii, Dokita Marcus Ogunbiyi, o sọ pe ayẹyẹ ikẹkọọjade ọhun kọja bi wọn ṣe roo, nitori o tun fi igbelewọn ipa pataki tileewe yii, ti ko lorileede nipasẹ ohun ọgbin lọna to ba ode onii mu.

Aarẹ Tinubu tun kan sara si awọn alaṣẹ  imọ ọgbin nipa eto ẹkọ, iṣẹ iwaadi wọn, eyi to ti tan kaakiri agbaye, to si jẹ ki wọn gba yunifasiti to dara ju nilẹ Afirika ati ipo keje lagbaaye ninu awọn yunifasiti onimọ ọgbin iyẹn lọdun 2024.

Bẹẹ lo tun fi idunnu sọ lọjọ naa pe ileewe yii lara awọn yunifasiti mẹwaa ti wọn ṣe daadaa nipa kikọ ati ipo kin in ni fun idagbasoke lọdun 2024.

O fikun ọrọ pe iru ileewe yunifasiti imọ ọgbin yii jẹ ọkan lara eyi to le koju ipenija lori ipese ounjẹ, iwoye oju ọjọ, igbooro ikaniyan ati bẹẹbẹẹ lọ.

O waa gba wọn niyanju lati tẹsiwaju lori gbogbo awọn nnkan ti wọn n ṣe to fi n mu wọn tayọ laarin awọn ẹlẹgbẹ wọn yooku.

Ki wọn si maa jẹ aṣiwaju lori awọn eto ti wọn da wọle lawọn ẹka ile ẹkọ wọn.

Ninu iṣẹ ti minisita fọrọ ẹkọ, Dokita Maruf Alausa, eyi ti Ọjọgbọn Kayọde Adebọwale, ọga yunifasiti Ibadan jẹ, loun naa tun ti gboriyin fun ileewe naa lori bi  wọn ṣe pese awọn akẹkọjade fun ikora ẹni nijanu ati ifigagbaga lagbaaye.

Minisita naa tun gboṣuba fawọn alaṣẹ ileewe ọhun bẹrẹ latori Ọjọgbọn Babatunde Kẹhinde to jẹ ọga agba ileewe ọhun, Ọba Rasheed Ayọtunde Ọlabomi, Odundun IV, Aragbiji tilẹ Iragbiji, fawọn ipa wọn lori ileewe naa.

Bẹẹ lo ni ileewe naa n ri iranwọ gba latọdọ ijọba apapọ nipaṣẹ ẹyawo ati TESFUND.

Ko to to akoko yii ni Ọba Ayọtunde to jẹ kanselọ nileewe naa ti ki awọn akẹkọọ-jade ku oriire ti wọn ṣe bẹẹ lo gba wọn niyanju lati ṣamulo awọn ẹkọ ti wọn kọ yii ki wọn si jẹ aṣoju rere fun ileewe ti wọn ti jade.

Ninu ọrọ Ọjọgbọn Babatunde Kẹhinde, ọga agba ileewe naa lo tun ti mẹnuba awọn aṣeyọri nla ti ko lẹgbẹ tileewe naa ti ṣe sẹyin, eyi to ti mu ogo bawọn kaakiri.


No comments:

Post a Comment

Pages