Yayi gboriyin fun Aarẹ Tinubu lori awọn atunṣe rere to ti mu ba orileede yii nipasẹ ọrọ aje - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 3 January 2026

Yayi gboriyin fun Aarẹ Tinubu lori awọn atunṣe rere to ti mu ba orileede yii nipasẹ ọrọ aje

Aṣofin Ọlalekan Solomon Adeọla Yayi to n ṣoju ẹkun West nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja, ti gboriyin fun aarẹ orileede yii, Aṣiwaju Bla Ahmed Tinubu lori erongba ẹ fun owo ori ati yiyọ afikun owo epo iyẹn sọbsidi, o ni o ti jẹ ki orileede yii ti ni apamọ owo to le ni tiriliọnu mẹwaa naira.

Aṣofin naa sọrọ yii lakooko idupẹ ọdun to ṣe lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii niluu Ilaro, nipinlẹ Ogun.

O sọ pe gbese biliọnu mẹjọ ni Naijiria jẹ ko to di pe wọn yọ sọbsidi kuro lori ọrọ epo, eyi to ki gbese ẹ to tiriliọnu mẹwaa naira lọdun.

Yayi sọ pe idunnu lo jẹ foun pe ifọkanbale ti n de ba ọrọ aje wa, ti irọrun si ti bẹrẹ si fẹẹ maa de fun gbogbo mutumuwa.

O ṣalaye pe  lara atunṣe tijọba Tinubu ti ṣe ni ti ọna Eko si Calabar ati Ṣokoto si Badagry, to ṣapejuwe gẹgẹ bi idagbasoke ati imayedẹrun fawọn araalu.

O tun waa gboriyin fun Aarẹ Tinubu lori awọn erongba atunṣe lati sọ orileede yii di tuntun ti yoo ṣiṣẹ ọpọ eeyan  .

Bakan naa lo tun lo akoko naa lati fi gboriyin fun Gomina  Dapọ Abiọdun fawọn akanṣe iṣẹ to ti ṣe paapaa julọ papakọ ofurufu  ti Gateway, eyi to ni yoo tunbọ jẹ ki ọrọ aje tun lọ soke si.

Ninu ọrọ Kunle Isiaq Salakọ, minisita feto ilera nibi ayẹyẹ idupẹ ọhun lo ti mẹnuba pe ayipada rere ti n ba orileede yii nipa ọrọ epo pẹtiroolu, pe ko si pe wọn n to ra epo mọ. Ati pe igbesẹ lati fopin si eto aabo to mẹhẹ n lọ lọwọ.

O waa gba awọn alatako oṣelu nimọran lati wa nnkan mii sọ, ki wọn jawọ lori isọkusọ nipa ẹgbẹ oṣelu APC.

Ko to to akoko yii ni  Ẹni ọwọ Michel Oluwarombi, tijọ Cathedral Church of Christ, ninu iwaasu ẹ lo ti gba Yayi lamọran lati tẹsiwaju ninu idupẹ ẹ si Ọlọrun nigba gbogbo.

O ni nnkan pataki mu  aṣeyọri  ba Yayi nigba gbogbo ni aye to n fi silẹ fun Ọlọrun lati dupẹ.
Ọpọ awọn eeyan jakanjakan lawujọ to fi mọ ẹlẹgbẹjẹgbẹ to nii ṣe pẹlu Yayi ni wọn wa nibẹ lọjọ naa.

No comments:

Post a Comment

Pages