Sẹnetọ Gbenga Daniel bẹbẹ fun iṣọkan awọn ọmọ ilẹ Ijẹbu lori ipinlẹ tuntun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 11 January 2026

Sẹnetọ Gbenga Daniel bẹbẹ fun iṣọkan awọn ọmọ ilẹ Ijẹbu lori ipinlẹ tuntun.

Aṣofin Gbenga Daniel to n ṣoju ẹkun Ogun East nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja, tun ti rọ gbogbo awọn ọmọ ilẹ Ijẹbu lapapọ lati wa ni iṣọkan ki erongba wọn lati di ipinlẹ tuntun le di mimuṣẹ.

Ijọba ibilẹ Odogbolu lo ti sọrọ naa lakooko to gbe abẹwo to n ṣe kaakiri awọn ijọba ibilẹ to wa labẹ Ogun West de ọhun eyi ti wọn pe ni BAT/OGD Movement.

O sọ pe ibi ti nnkan duro de lori ọrọ idasilẹ ipinlẹ tuntun Ijẹbu eyi to pe ni ireti igbẹyin lo ni yoo tubọ mu idagbasoke ba gbogbo ilẹ naa, iyẹn ti wọn ba jẹ ko tẹ wọn lọwọ.

O ṣalaye pe aṣeyọri nla ni yoo tun jẹ fun gbogbo ijọba ibilẹ mẹsẹsan to wa labẹ Ogun East, ti idasilẹ ipinlẹ Ijẹbu ọhun ba di ootọ ti yoo si tun mu isọkan wa pẹlu.

Ṣugbọn nnkan ẹyọ kan ṣoṣo to le mu abude ba a ni ti gbogbo wọn ko ba jọ wa ni irẹpọ.

Aṣofin Daniel to tun ti figba kan jẹ gomina nipinlẹ Ogun tun ran awọn eeyan leti awọn iṣẹ akanṣe nla lto ṣe lakooko to fi wa nipo gomina fun odidi ọdun mẹjọ iyẹn laarin ọdun 2003 si 2007. Lara ẹ ni idasilẹ yunifasiti Tai Ṣolarin to wa ni Ijagun ati ileewe awọn olukọni to wa ni Omu.

Bakan naa lawọn tun ṣe imayedẹrun fawọn ileewe kọọkan nilẹ Ijẹbu, eyi to ni wọn ṣi n jẹ anfaani ẹ di oni.

O fikun pe awọn iṣẹ abẹlẹ kan si n lọ lọwọ lori ọrọ idasilẹ ipinlẹ Ijẹbu, toun kan yẹra lati maa pariwo ẹ sita, titi ti wọn yoo fi yanju gbogbo ẹ.

O wa sọ pe igbesẹ ti fẹẹ pari lori orukọ ati oluulu ti wọn yoo sọ ipinlẹ naa ṣugbọn tawọn si n pe ni Ijẹbu- Rẹmọ naa.

Daniel lo akoko naa lati kilọ fawọn alagabagebe eeyan ti wọn ko fẹẹ ki erongba naa waye nitori imọtara ẹni ti wọn nikan.

Bẹẹ lo wa kesi gbogbo awọn araalu lati jade sita ki wọn kopa ninu iforukọsilẹ ẹgbẹ oṣelu APC,eyi ti yoo bẹrẹ laipẹ.

Ki wọn si fọwọsowọpọ lati ṣatiilẹyin fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu fun ibo aarẹ ọdun 2027.

No comments:

Post a Comment

Pages