Iṣẹlẹ kan lo waye lọjọ Aiku Sannde, to kọja yii ni agbo oṣelu, eyi to si jẹ pe titi di akoko yii ni wọn ṣi n royin, ti wọn lo si ti ko awọn kan sinu aibalẹ ọkan.
Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun lo ṣayẹyẹ ọjọọbi ọdun kejidinlaadọrin to dele aye.
Ki i ṣe pe ọ ṣẹṣẹ maa n dana ariya ọjọọbi tawọn eeyan paapaa julọ awọn alatilẹyin ẹ nidii oṣelu ti maa wa n ba a ṣajọyọ.
Ṣugbọn eleyii ti wọn ṣe ni aafin Ake yii yatọ latigba to ti gbe ijọba kalẹ, ṣe ni ero pọ rẹpẹtẹ debi pe ilu Abẹokuta mọ pe wọn n ṣe nnkan.
Bo tilẹ jẹ pe oriṣiriṣii ahesọ lo ti n lọ nigboro ko to di ọjọ naa, bawọn kan ṣe n sọ pe o fẹẹ fi ọjọ naa polongo ara ẹ pe o fẹẹ jade dupo fun aṣofin agba ni ẹkun aarin gbungbun Ogun iyẹn Ogun Central fun ibo ọdun 2027.
Bẹẹ lawọn kan sọ pe ipolongo lasan pe o ṣi wa ninu oṣelu lo fẹẹ fi ọjọọbi naa ṣe, amọ ju gbogbo ẹ lọ ayẹyẹ ọjọọbi naa yatọ gẹgẹ bi awọn kan ninu oṣelu ṣe roo.
A fi bi ẹni pe ọkunrin naa ṣi wa nipo ninu oṣelu lawọn eeyan ṣe pọ, ti wọn lo si n jẹ ikunsinu fawọn kan ti wọn jọ wa ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni Ogun.
Ohun ta a tiẹ kọkọ gbọ ni idunkoko tawọn agba ẹ kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC dun mọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa pe ẹnikẹni to ba yọju sibi ayẹyẹ ọjọọbi Amosun yoo ri pipọn oju ẹgbẹ.
Alẹ ọjọ Abamẹta, Satide, o ku ọla ni wọn lawọn agba ẹgbẹ ọhun fi ohun ranṣẹ lori foonu lati kilọ fun pe wọn ko gbọdọ yọju.
Amọ tawọn ọmọ ẹgbẹ ọhun ka ọrọ naa si aja lo n gbo, to fi jẹ pe gbogbo wọọdu to wa nipinlẹ Ogun ni wọn ti sibi ayẹyẹ ọjọọbi ibi ọhun.
Ninu ọrọ Amosun lọjọ naa lo ti sọ pe ko si oootọ ninu ọrọ tawọn kan sọ pe oun wa ninu ẹgbẹ ADC, o ni digbi loun ṣi wa ni APC, toun ko yẹsẹ
O sọ pe lẹyin Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba, oun si ni ẹnikeji tawọn jọ da APC silẹ nipinlẹ Ogun, ko si sẹni to le le oun jade.
Bakan naa lo tun atilẹyin ẹ han si ipadabọ Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, fun saa keji ninu ibo ọdun 2027.
No comments:
Post a Comment