Ẹdun ọkan nla lo n jẹ fawọn eeyan ilẹ Ẹgba, nitori bawọn ọna wọn kan ṣe ti panpẹ iku to si jẹ pe kaka ki wọn wa ojutu sii ṣe ni wọn pa a ti, tijọba ko ṣe nnkankan le lori.
Idi niyi tawọn kan ti wọn pe ni apero ọmọ Ẹgba, iyẹn Ẹgba Summit, ṣe fi lẹta ranṣẹ sawọn agbaagba wọn kan, to fi mọ awọn ọba wọn lati bawọn parọwa si minisita fọrọ iṣẹ lorileede yii lati tete ṣatunṣe lee lori.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, awọn ọna ti wọn ti pati ọhun to ti di ifoya fawọn araalu lati maa gba ni Idi Aba si OGTV lọ si Ajebọ si oju ọna marosẹ Ọbafẹmi Owode, to wa niluu Abẹokuta.
Lẹta ọhun eyi ti aarẹ ẹgbẹ naa, Dokita Gbenga Adeoye fọwọ si lo ti rọ awọn ọba alaye to fi mọ Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun, Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba, lati lo ipo wọn wa ọna abayọ si ipenija ti wọn n koju.
Ẹgbẹ apero Ẹgba ti kọkọ gboriyin fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu atawọn ti wọn jọ n ṣejọba lori ilakaka wọn fun idagbasoke ọrọ aje.
O waa ni awọn pakiyesi wọn lori idojukọ wọn lori awọn ọna ti wọn ti pa ti ọhun, eyi ti wọn sọ pe o le mu ifasẹyin ati adinku ba ọrọ aje.
Bakan naa ni Dokita Adeoye tun mẹnuba a pe latigba ti Aarẹ tẹlẹ lorileede yii, Oloogbe Mohammadu Buhari ti wa nipo ni wọn ti gbe iṣẹ akanṣe awọn ọna yii fun, to si jẹ pe titi di akoko yii, wọn ti ds a duro, ti wọn ko fọwọ kan mọ.
Wọn waa rọ minisita fọrọ iṣẹ lati tete gbe igbesẹ le lori, nitori ki ọrọ aje tun le gberu sii
No comments:
Post a Comment