Ìpo Awùjalẹ̀ yẹ fún ìbọwọ fún àṣà, kì í ṣe ìtànjẹ́ láti ọwọ́ àwọn alákóso òṣèlú- Ọtunba Rotimi Paṣeda - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 23 January 2026

Ìpo Awùjalẹ̀ yẹ fún ìbọwọ fún àṣà, kì í ṣe ìtànjẹ́ láti ọwọ́ àwọn alákóso òṣèlú- Ọtunba Rotimi Paṣeda



Agba oṣelu nni, Ọtunba Rotimi Paṣeda,ti sọ pe ọkan lara ipo ọba ti ko ṣe yẹyẹ tabi dagunla si, to nii ṣe pẹlu ibọwọ fun aṣa nilẹ Yoruba, ni Awujalẹ, nitori eyi, ko yẹ kawọn to n ṣakoso nipa oṣelu mu ẹmi itanjẹ wọn wọ.

Ninu atẹjade kan to fi sita lo ti fi aidunnu ẹ han lori bawọn kan ṣe fẹẹ ma tọwọ oṣelu bọ yiyan Awujalẹ tilẹ Ijẹbu, eyi to sọ pe ko yẹ ko ri bẹ.

O sọ pe bigba ti wọn  fẹẹ ba aṣa ati ilana to ti fidimulẹ nilẹ Yoruba jẹ ni.O ni lẹyin ti Awujalẹ to ti wa nibẹ tẹlẹ, Ọba Sikiru Adetọna waja, ninu oṣu keje, ọdun to kọja, nigba to lo ọdun marundinlọgọta lori oye.

O ni "Lẹ́yìn naa ni ipo Awujalẹ ti ṣofo,ti ilana to tọ fun yíyan ọba tuntun sì ti bẹrẹ laaarín Ile-ọba Fusengbuwa, eyí tawọn ọmọ-ọba to yẹ lati dije ti jade fun ayẹwo fawọn afọbajẹ

Ọtunba Paṣeda ni dipo ki wọn jẹ ki aṣa gbe ọna tiẹ, ẹdun ọkan lo jẹ bi ijọba ipinlẹ Ogun ṣe ti da ilana yíyan duro lẹẹmejì, nípa idi ti wọn pe ní ẹbẹ, aníyàn aabo ati ẹsun pe a ko tẹle ilana daadaa. 

O ni idaduro to ṣẹṣẹ ju u lọ, ti wọn kede ní oṣu kin in ni, ọdun 2026, wa lẹyin awọn ẹbẹ—pẹlu ẹbẹ kan lati ọwọ olorin fújì nni, W,asiu Ayinde Marshall (KWAM 1), ti bẹbẹ pe ki ijọba da ilana naa duro.

Paṣeda sọ pe nnkan ti eleyii tumọ si ni pe wọn ti fẹẹ mu ewu to n yi ile-ọba mímọ padà sí ohun elo ti oṣelu.

O ni, "Nínú àṣà Yorùbá, yíyan ọba kì í ṣe ohun tí àṣẹ ìjọba lè paṣẹ fún. Nígbà tí ìyípo bá dé sí ilé-ọba kan, àwọn ọmọ-ọba tó yẹ máa pàdé lábẹ́ àṣà àti òfin láti yan àwọn olùdíje, tí àwọn afọ̀bàjẹ yóò sì ṣe àyẹ̀wò àti yàn ẹni tí àyànmọ́ fọwọ́ sí. 

"Mimu olùdíje kan lórí nípa àwọn alákóso ìjọba yóò jẹ́ wahala taara sí ètò yìí. Ilé-ọba Fusengbuwa ti kìlọ̀ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa kọ̀, láti gba ìgbìmọ̀ kankan tí ìjọba bá gbìyànjú láti fi olùdíje kan lé ilẹ̀ Ìjẹ̀bú lórí, wọ́n sì tẹ̀numọ́ pé àṣà àti òfin nìkan ló yẹ kí ó darí ìlànà náà. 

"Ìtàn ti fi hàn pé ìfarahàn ìjọba amúnisin àti ti ìjọba lẹ́yìn òmìnira sínú ọba Yorùbá máa ń bà aṣẹ àti ìtẹ́wọ́gbà jẹ́, ó sì máa ń dá àìdúróṣinṣin pípẹ́ sílẹ̀".

 Ẹni to t figba kan jẹ oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu UPN nipinlẹ Ogun, tun sọ pe gẹgẹ bi awọn alakoso amunisin ṣe n fọwọ sí ilana ìtẹsiwaju lati ṣakoso oṣelu, bẹẹ naa ni o fara han pe wọn fẹẹ maa dunkoko
mọ́ ìpìlẹ̀ ẹ̀mí àti àṣà ilé-ọba Awùjalẹ̀. 

 O ni, "Nígbà tàwọn olóṣèlú bá fi ara wọn sínú àwọn ìlànà mímọ́, abajade ni ìdàrúdàpọ̀, ìpínya, àti ìpadanu ìbòwò fún ipo ọba tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ilẹ̀ Ìjẹ̀bú ń bẹ̀rù.

"Ìjọba ń sọ pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún “àlàáfíà, ìtẹ́lọ́run àti ìṣàkóso rere,” ṣùgbọ́n èyí kò gbọ́dọ̀ jẹ́ àṣiírí láti fọ́ àṣà ìbílẹ̀ tó ṣòro kedere. Ìtẹ́ Awùjalẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ​​àwọn ìtẹ́ tí a bọ́lá jù lọ ní Yorùba"
.
Paṣeda ṣafikun ọrọ ẹ pe bawọn oloṣelu ṣe n ṣaṣoju han lati fi idunkoko yi itẹ ọba si ọfiisi oṣelu dipo ki wọn jẹ ko jẹ ami aṣa ti yoo mu iṣọkan ba gbogbo eeyan.

O gba awọn alakoso oṣelu lati tẹle ohun ti ilana ati aṣa sọ nipa iyansipo ọba Awujalẹ, ki wọn si jẹ ki awọn araalu pinnu ẹni ti yoo de ade kì í ṣe ẹ̀bẹ̀ sí gomina tàbí àṣẹ láti ilé-ìjọba ìpínlẹ̀.

O ni igbesẹ pe ki igbimọ  kankan fẹẹ gbe  olùdíje kan lé lórí tàbí láti gba àṣẹ àṣà lọ́wọ́ yóò jẹ́ ohun tí ilẹ̀ Ìjẹ̀bú àti gbogbo àwọn olólùfẹ́ àṣà Yorùbá yóò kọ̀.



No comments:

Post a Comment

Pages