Idi ti ileewe yunifasiti imọ ọgbin FUNAAB ṣe fojoojumọ goke agba- Ọjọgbọn Kẹhinde - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 29 January 2026

Idi ti ileewe yunifasiti imọ ọgbin FUNAAB ṣe fojoojumọ goke agba- Ọjọgbọn Kẹhinde

Ọjọgbọn Oluṣọla Kẹhinde, ọga agba ileewe giga yunifasiti fun imọ ọgbin to wa niluu Abẹokuta iyẹn FUNAAB, ti fi idunnu ẹ han lori bi ileewe ọhun ṣe n fojoojumọ tawọn ẹgbẹ ẹ yọ latigba ti wọn ti da silẹ.

Bẹẹ lo sọ pe o le ni ẹgbẹrun mẹrin ti wọn yoo kẹkọọ jade nibi ayẹyẹ ikẹkọọ jade wọn ti yoo waye lọjọ Satide, Abamẹta yii.

Nibi ipade oniroyin to waye lọgba ileewe naa fun ti ayẹyẹ ikẹkọọ jade awọn ọmọleewe ti yoo waye naa lo ti mẹnuba awọn ọrọ yii.

O tun sọ pe o le ni ẹgbẹrun mẹfa akẹkọọ ti wọn ṣẹṣẹ gba wọle lọdun to kọja fun saa tuntun, eyi to jẹ pe o ti fẹẹ pọ ju lọgba ileewe naa.

Ọga agba ọhun tun ṣalaye siwaju pe igbooro ẹkọ wọn tun ti di mẹrinlelogoji, lawọn ẹka marundinlọgọta nileewe yunifasiti FUNAAB, labẹ aṣẹ ajọ to n ṣamojuto yunifasiti lorileede yii iyẹn NUC.

O sọ pe awọn nnkan to n jẹ ki o rọrun fawọn akẹkọọ ko ṣe e lẹyin iranwọ ti wọn ri gba lati ajọ NELFUND, eyi to ti to ẹgbẹrun marun-un akẹkọọ to ti janfaani ẹ.

Bakan naa lo sọ pe awọn ko fọwọ yẹpẹrẹ mu eto aabo nileewe naa, nitori ẹ si iwa ọdaran ko fi bẹẹ wọpọ.

Ọjọgbọn Kẹhinde tun ṣalaye siwaju pe ajọṣepọ to danmọran lo wa laaarin ileewe ọhun atawọn araalu to yi wọn po ati pe ọpọ wọn ni wọn ti ṣeranwọ ti apa wọn ka nipasẹ ọna ti ko dara.

O waa sọ pe ọpọ iṣẹ iwadii  wọn tun ti jẹ ki ileewe FUNAAB tun sun siwaju ju bo ṣe wa  tẹlẹ lọ

O lo akoko naa lati gboriyin fawọn oṣiṣẹ inu ọgba ọhun to fi mọ awọn olukọni atawọn akẹkọọ fun ifọwọsowọpọ wọn lati le jẹ ki idagbasoke tẹsiwaju nileewe imọ ọgbin to wa ni Abẹokuta.

No comments:

Post a Comment

Pages