Fun ọpọ wakati ni nnkan ko fi rọgbọ lagbegbe Akokoro, ni Iwoye, nijọba ibilẹ Imẹkọ-Afọn, nipinlẹ Ogun, nigba tawọn afurasi onifayawọ to n gbe oogun oloro doju ija kọ awọn oṣiṣẹ aṣọbode, ti meji si farapa yannayanna.
Gẹgẹ bi atẹjade ti agbẹnusọ asọbode nipinlẹ naa, Zakari Chado fi sita, iṣẹlẹ ọhun lo sọ pe o waye l'Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja.
Wọn ni ṣe lawọn oṣiṣẹ aṣọbode to n sọ agbegbe yii ṣadeede ṣakiyesi tirọọki nla, to kun fun oogun oloro ti wọn fẹẹ ko wọlu.
Loju ẹsẹ ni wọn lawọn to ko oogun oloro naa wọlu, ti sare lọọ pe awọn ọmọọta ti wọn si doju ija kọ awọn ẹṣọ aṣọbode yii.
Ṣe ni wọn sọ pe awọn afurasi da ina ibọn bolẹ ti wọn si yin in lu taya mọtọ, aṣọbode, ti ọrọ di ija nla laaarin awọn mejeeji.
Meji ninu awọn aṣọbode lo farapa ti wọn si ti gbe wọn lọ si ọsibitu, nibi ti wọn ti n gba itọju.
Iwadii tun fi ye wa pe awọn afurasi naa salọ pẹlu tirọọki nla ti wọn fi gbe oogun naa wọlu.
Chado ti wa sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ ọhun pẹlu ileri pe ọwọ yoo tẹ awọn afurasi naa pẹlu tirọọki wọn.
Bakan lo sọ pe ọga agba wọn nipinlẹ Ogun, Olukayọde Afẹni, ti fi aidunnu ẹ han lori iṣẹlẹ naa, o ti waa ke si awọn ọba alaye atawọn olori ilu pe ki wọn kilọ fawọn ọmọ wọn to n ṣe fayawọ, ti wọn fẹẹ maa kọju ija sawọn, ki wọn lọ so ọwọ mọ wọn bọ aṣọ.
No comments:
Post a Comment