Ajo to n ṣe apero lori eto ọrọ aje nilẹ Ẹgba fẹẹ kijọba apapọ pari iṣẹ lori awọn akanṣe ọna l' Abẹokuta - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 21 January 2026

Ajo to n ṣe apero lori eto ọrọ aje nilẹ Ẹgba fẹẹ kijọba apapọ pari iṣẹ lori awọn akanṣe ọna l' Abẹokuta

Ẹdun ọkan nla lo n jẹ fawọn eeyan ilẹ Ẹgba, nitori bawọn ọna wọn kan ṣe ti panpẹ iku to si jẹ pe kaka ki wọn wa ojutu sii ṣe ni wọn pa a ti, tijọba ko ṣe nnkankan le lori.

 Idi niyi tawọn ajọ kan ti wọn pe ni apero ọrọ aje nilẹ Ẹgba, iyẹn Ẹgba Summit, ṣe fi lẹta ranṣẹ sawọn agbaagba wọn kan, to fi mọ awọn ọba wọn lati bawọn parọwa si minisita fọrọ iṣẹ lorileede yii lati tete ṣatunṣe lee lori.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, awọn ọna ti wọn ti pati ọhun to ti di ifoya fawọn araalu lati maa gba ni Idi Aba si OGTV lọ si Ajebọ si oju ọna marosẹ Ọbafẹmi Owode, to wa niluu Abẹokuta.

Lẹta ọhun eyi ti aarẹ ẹgbẹ naa, Dokita Gbenga Adeoye fọwọ si lo ti rọ awọn ọba alaye  to fi mọ Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun, Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba, lati lo ipo wọn wa ọna abayọ si ipenija ti wọn n koju.
Ẹgbẹ apero Ẹgba ti kọkọ gboriyin fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu atawọn ti wọn jọ n ṣejọba lori ilakaka wọn fun idagbasoke ọrọ aje.

O waa ni awọn pakiyesi wọn lori idojukọ wọn lori awọn ọna ti wọn ti pa ti ọhun, eyi ti wọn sọ pe o le mu ifasẹyin ati adinku ba ọrọ aje.

Bakan naa ni Dokita Adeoye tun mẹnuba a pe  latigba ti Aarẹ tẹlẹ lorileede yii, Oloogbe Mohammadu Buhari ti wa nipo ni wọn ti gbe iṣẹ akanṣe awọn ọna yii fun, to si jẹ pe titi di akoko yii, wọn ti ds a duro, ti wọn ko fọwọ kan mọ.

Bẹẹ ni Adeoye la ọna mẹjọ kalẹ idi tswọn iṣẹ akanṣe ti wọn n fi wọlẹ naa ṣe ṣe pataki to.

Akọkọ ni pe latigba ti Aarẹ Mohamadu Buhati, to ti do oloogbe bayii ti wa lori ipo ni wọn ti gbe awọn iṣẹ agbṣe ọhun fawọn alagbaṣe.

Ẹlẹẹkeji ni pe ọna to lọ lati FMC Idi Aba kọ si Chrisland si dara tẹlẹ, ko to di pe o ti wa di iṣoro fawọn araalu latigba.

Ikẹta ni ileewe ẹkọṣe oogun tijọba apapọ ṣẹṣẹ da silẹ to to ogoje eekan ni yoo ṣoro lati lọ sibẹ nitori ọna ibi to wa iyẹn abule Ajibayọ ti wọn daṣẹ duro nibẹ.

Ẹlẹẹkẹrin ọna kan ṣoṣo to jẹ eyi ti wọn le gba lati Abẹokuta si Ibadan, iyẹn Ọdẹda Ilugun si Apata naa ko bojumu.

Bakan naa ọna to lọ sileeṣẹ tẹlifiṣan OGTV, Ogere, to  jẹ pe ti wọn ba yanju ẹ ni yoo mu ibadan si Ṣagamu rọrun.

Bẹẹ ni wọn sọ pe bi wọn ṣe n pin awọn ọna lakooko yii imu mura inira gidi bawọn  onimọto lakooko yii, eyi ti wọn sọ pe ko ri bẹẹ nigba iṣejọba Oluṣẹgun Ọṣọba nigba to n ṣe gomina.

 Pẹlu eyii wọn rọ ileeṣẹ to n ri si ọna lati tete gbe igbesẹ lori awọn ọna yii, ki itura le de ba araalu.

Bẹẹ ni Adeoye la ọna mẹjọ kalẹ idi tswọn iṣẹ akanṣe ti wọn n fi wọlẹ naa ṣe ṣe pataki to.

Akọkọ ni pe latigba ti Aarẹ Mohamadu Buhati, to ti do oloogbe bayii ti wa lori ipo ni wọn ti gbe awọn iṣẹ agbṣe ọhun fawọn alagbaṣe

Ẹlẹẹkeji ni pe ọna to lọ lati FMC Idi Aba kọ si Chrisland si dara tẹlẹ, ko to di pe o ti wa di iṣoro fawọn araalu latigba.

Ikẹta ni ileewe ẹkọṣe oogun tijọba apapọ ṣẹṣẹ da silẹ to to ogoje eekan ni yoo ṣoro lati lọ sibẹ nitori ọna ibi to wa iyẹn abule Ajibayọ ti wọn daṣẹ duro nibẹ.

Ẹlẹẹkẹrin ọna kan ṣoṣo to jẹ eyi ti wọn le gba lati Abẹokuta si Ibadan, iyẹn Ọdẹda Ilugun si Apata naa ko bojumu.

Bakan naa ọna to lọ sileeṣẹ tẹlifiṣan OGTV, Ogere, to  jẹ pe ti wọn ba yanju ẹ ni yoo mu ibadan si Ṣagamu rọrun.

Bẹẹ ni wọn sọ pe bi wọn ṣe n pin awọn ọna lakooko yii imu mura inira gidi bawọn  onimọto lakooko yii, eyi ti wọn sọ pe ko ri bẹẹ nigba iṣejọba Oluṣẹgun Ọṣọba nigba to n ṣe gomina.
 
Pẹlu eyii wọn rọ ileeṣẹ to n ri si ọna lati tete gbe igbesẹ lori awọn ọna yii, ki itura le de ba araalu

No comments:

Post a Comment

Pages