Ṣe ni ẹsẹ o gbero laduugbo Arokojẹ,Ọbantoko niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, nigba ti Fadilat Shakykh, Alaaji Zakariyah Idris Imọdọla tọpọ awọn eeyan mọ si Kandayasu, ti ijọ JAMHIYATUL FATIHATUL KHARAAT ṣayẹyẹ onibeji lọjọ Aiku Sannde, ana
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọjọ naa ni wọn ṣayẹyẹ ọjọọbi Anọbi Mohammad iyẹn Malud Nabiyy, bẹẹ naa ni wọn tun ṣefilọlẹ kikọ mọṣalaṣi tuntun si adugbo naa.
Ninu ọrọ Kandayasu nibi ayẹyẹ ọhun lo ti dupẹ lọwọ Allah fun idasi ẹ lati bii ọdun mẹẹdogun sẹyin ti wọn ti da ijọ naa silẹ.
O sọ pe gẹgẹ bi gbogbo wa ṣe mọ pe Ọlọrun lo ni igba ati akoko pẹlu ọjọ, o nigba ti Ọlọrun sọ pe akoko ti to lati kọ mọṣalasi naa ree tawọn fi pe eeyan fun ifilọlẹ ẹ.
Alaaji Imọdọla tun fi kun ọrọ ẹ pe lori bawọn kan ṣe n ṣe ayẹyẹ ọjọọbi Anabi, o sọ pe ẹni to gbe iṣẹ Ọlọrun da ni yatọ sẹni to gbe tara ẹ ati pe iṣeṣi ẹni to ba ṣe ti Ọlọrun maa yatọ gedegbe si ẹni to n ṣe tara ẹ.
O ni nitori ẹ lawọn ṣe n ṣe nnkan ti wọn ṣe lonii ati pe ki i ṣe nitori owo, nitori Ọlọrun n bo aṣiri wọn.
O tun sọ pe lọpọ igba eeyan maa fi bọ sita lati ṣe afihan ijọ to ni, ibi to wa ati bo ṣe n ṣe igbesi aye oun.
Bakan naa lo tun mẹnuba afojusun ọjọ iwaju fun itẹsiwaju ẹsin islam, o lawọn n gbero lati kọ ibi tawọn ọmọ yoo ti maa kọ keu, nitori ki wọn ma baa ya iyakuya lọjọ iwaju.
Nnu ọrọ Oloye Joju Fadairo, olufilọlẹ pataki lọjọ naa lo ti ba oni nnkan ẹyẹ ọjọ naa yọ paapaa fun ti ifilọlẹ mọṣalaṣi tuntun ti wọn fi le lẹ lọjọ naa.
Ọ sọ pe ko si iyapa kankan ninu ẹsin musulumi ati igbagbọ nitori ọmọọya kan naa ni wọn ati pe o yẹ ki wọn jọ maa gbe ni irẹpọ ati ifẹ.
O fikun ninu ọrọ ẹ pe ko wahala ẹsin ko le waye nilẹ Yoruba nibi nitori wọn ti wọnu ara wọn ninu ẹbi, ko si idile kan ti ẹsin mejeeji ko wa.
O wa gbadura pe Ọlọrun yoo pari mọṣalaṣi ọhun layọ ati alaafia pẹlu ileri pe ti wọn ba pari ẹ, oun yoo wa ba wọn gbadura nibẹ.
Ṣugbọn ni ti Alaaji Mutiu Afọd, toun naa jẹ ọkan lara olufilọlẹ ọjọ naa lo ti ba Sheu Kandayasu dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ọjọọbi Malud Nabyy ati ayẹyẹ ọdun kẹẹdogun to da ijọ naa silẹ.
Nigba to n ṣapejuwe Kandayasu, o sọ pe ko digba taa ba pariwo tabi rojọ, ti Ọlọrun ba ti ṣe eeyan lẹni rere, o ṣe bẹẹ ni, bakan naa to ba ti ṣe laṣiwaju rere.
O ni latigba ti ọkunrin naa ti de Abẹokuta, ni Ọlọrun ti gba fun, ti gbogbo awọn araalu naa gba fun ni. O ni o tun jẹ oninure, to n ṣaanu fawọn eeyan.
Lara awọn to wa nibẹ lọjọ naa ni Alaaji Sheu Lukman, Alaaji Olowoṣile, Immam Tẹjumọla, Alaaji Lukman Booseere, Imaam Ibrahim Balogun,Imaam Yusuf, Imam Ibrahim CBN,Ọgbẹni Kẹhinde, to jẹ igbakeji ọga agba imigireṣan.
No comments:
Post a Comment