Nibi ayẹyẹ gbigba akoso lọwọ ẹni to ti wa nibẹ, Godwin Ọtunla, lo ti ṣeleri pe oun yoo tubọ ṣamulo awọn aṣeyọri ti ẹni to ti wa nibẹ ti ṣe gẹgẹ bi atẹgun nla.
O sọ pe gbogbo akitiyan oun ni lati fopin si iwa fayawọ lati dinku nipinlẹ ọhun ati lati r pe ipawo wọle si osuwọn ijọba tunbọ peleke si.
Ọga agba tuntun ọhun ṣalaye siwaju sii pe labẹ isakoso ẹni to n gbaṣẹ lọwọ ẹ gbogbo ọna lo gba lati rii pe idagbasoke deba iṣẹ aṣọbode nipasẹ ipawo wọle, mimu adinku ba iṣẹ fayawọ ati irẹpọ nla laarin awọn to mule ti wa, o ni irufẹ bẹẹ loun naa yoo dawọle.
O wa gboriyin fun Ọtunla fawọn iṣe to ti ṣe, ti akọsilẹ rẹ ko si ni parẹ lailai.
Ninu ọrọ idagbere Godwin Ọtunla, lo ti kọkọ dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ore-ọfẹ, to foun lakooko to fi jẹ ọga agba nibẹ.
Bẹẹ lo ro awọn oṣiṣẹ aṣọbode ipinlẹ Ogun, awọn akẹẹgbẹ wọn tawọn naa jẹ alaabo ilu, to fi mọ awọn ọba alaye lati fọwọsowọpọ pẹlu ọga agba tuntun yii
No comments:
Post a Comment