Ọdun Keresi: Ẹ jẹ ka fi ẹkọ ninu Kristi ṣapẹẹrẹ ihuwasi rere- Yayi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 24 December 2025

Ọdun Keresi: Ẹ jẹ ka fi ẹkọ ninu Kristi ṣapẹẹrẹ ihuwasi rere- Yayi


Sẹnetọ Ọlamilekan Solomon Adeọla, tọpọ mọ si Yayi, to n ṣoju ẹkun Ogun West nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja, ti tọ gbogbo awọn ọmọ orileede yii lati kọ ninu ọjọọbi Jesu Kristi lati fi ṣe apẹẹrẹ rere fun ihuwasi ọmọniyan lawujọ.

O sọrọ yii ninu iṣẹ fun ayẹyẹ ọdun keresi, o wa pe gbogbo ọmọlẹyin kristi atawọn ẹlẹsin yooku lati fi ayajọ ọdun ọhun duro gbọingbọin ninu igbagbọ wọn, ki wọn si tun fi gbadura fun aṣeyọri isakoso Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu.

Aṣofin Adeọla tun fi kun ninu ọrọ ẹ pe ohun ti ọdun keresi duro fun ni ọjọọbi Jesu, ẹni to wa fun igbala ẹmi ọkan awọn eeyan, eyi to sọ pe oun nigbagbọ pe igbala ọkan yii yoo jẹ tawọn eeyan ọjọ iwaju pẹlu.

O sọ pe " Mo ki gbogbo ọmọ lẹyin kristi jakejado ku ayẹyẹ ọdun keresi, bẹẹ ni mo rọ wọn ki wọn ma ṣe roo pe ọdun lasan bi ko ṣe pe ki wọn tun sunmọ Ọlọrun lati fi gbadura fun orileede yii pẹlu.
"Mo tun fẹẹ ki ẹ mọ pe awọn atunṣe erongba Aarẹ wa, Bọla Ahmed Tinubu, tun ti ṣaṣeyọri lawọn ẹka kan  paapaa julọ owo naira wa ati epo pẹtiroolu."

O waa pari ọrọ ẹ pe bo tilẹ jẹ pe loootọ lawọn ọmọ orileede yii n koju iṣoro ọrọ aje, to si bawọn finra gidi ṣugbọn idaniloju wa pe yoo di ohun itan nipasẹ ireti, igbagbọ ati ati adura.



No comments:

Post a Comment

Pages