Ọga agba fawọn ẹṣọ aṣọbode nipinlẹ Ogun, Ọladapọ Afẹni, tun ti kilọ fawọn fayawọ lati tete fi ipinlẹ naa silẹ nitori oun ṣetan lati maa foju wọn ri mabo.
Ọkunrin naa sọrọ yii nibi ipade oniroyin to waye ni oluleeṣẹ wọn to wa ni Idi iroko, nibi to ti mẹnuba awọn aṣeyọri to ṣe lẹnu igba to gba akoso.
O sọ pe gẹgẹ bi owe Yoruba to sọ pe oju bọrọ kọ ni wọn fi gbọmọ lọwọ ekurọ, o ni gbogbo igba lawọn aṣọbode yoo rii pe iwa fayawọ dinku lorileede wa, nitori bi wọn ṣe n mu ifasẹyin ba orileede wa.
Afẹni tun mẹnuba a pe ọpọ awọn ẹru ofin lọwọ awọn tun ti ba bii oogun oloro, aloku bata, baagi irẹsi, epo pupa, aloku taya atawọn nnkan mii ii.
O fikun ọrọ ẹ pe ọpọ awọn ayederu ounjẹ ti wọn ko wọle tawọn gba ni owo ẹ to miliọnu igba o le mọkanlelaadọrun naira.
Lara awọn agbegbe to sọ pe ọwọ ti bawọn ni ọna Lusada si Ado Odo, Abule Kazeem si Igbo ọra lọna Abẹokuta. Imẹkọ, Owode, Idi iroko, Ipokia atawọn ibo-miii.
Bakan naa lo sọ pe awọn tirela ati mọto ti wọn ko awọn ẹru ofin wọle nijọba apapọ yoo gbẹsẹ le.
Bẹẹ ni ọga agba aṣọbode ọhun tun gboriyin fawọn oṣiṣẹ lori bi wọn ko ṣe rẹwẹsi ọkan lati maa ṣiṣẹ wọn doju amin.
O waa dupẹ lọwọ awọn alaabo ilu yooku fun ifọwọsowọpọ wọn, eyi to jẹ ki wọn le ṣaṣeyọri
Afẹni waa ṣeleri pe awọn yoo tubọ duro gbọingbọin lati rii pe fayawọ dinku lawujọ. Lẹyin naa lo gbe awọn oogun oloro ti wọn gba le ọga agba to n gbogun ti oogun oloro, NDLEA, iyẹn Ọgbẹni Ekundayọ Williams.
No comments:
Post a Comment