Ẹgbẹ oṣelu Labour wa a bẹ Ṣẹgun Ṣowumi lati dije dupo gomina ninu ẹgbẹ wọn nipinlẹ Ogun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 19 December 2025

Ẹgbẹ oṣelu Labour wa a bẹ Ṣẹgun Ṣowumi lati dije dupo gomina ninu ẹgbẹ wọn nipinlẹ Ogun.

Ẹgbẹ oṣelu Labour nipinlẹ Ogun, ti wa bẹ oludasilẹ ẹgbẹ to n wa ọna abayọ iyẹn 'The Alternative' Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi lati darapọ mọ ẹgbẹ wọn ko le jade dupo gomina ninu ibo to n bọ lọdun 2027.

Ẹbẹ yii waye lakooko ti ẹgbẹ oṣelu ọhun ṣabẹwo lọ si ọdọ Sowunmi nile ẹ to wa ni Abẹokuta, lọjọ Ẹti, Furaide.

Alaga ẹgbẹ oṣelu Labour, Ọnarebu Arabinrin Oluwabukọla Ṣoyọye ati Kọmoreedi Abayọmi Arabambi, lo ṣaaju awọn eeyan ẹ wa sọdọ Ṣowunmi.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o lawọn rọ ọ bẹẹ lawọn bẹ lati darapọ mọ ẹgbẹ wọn ko si le jade dupo gomina iyẹn lọdun 2027.

O sọ pe akoko ti to fun iṣejọba tuntun ati pe awọn ri Ṣẹgun Ṣowunmi gẹgẹ bi ẹni to kun oju oṣuwọn lati mu ayipada rere ba ipinlẹ Ogun to ba depo gomina.

Alaga fẹgbẹ oṣelu Labour tun fi kun ọrọ ẹ pe ijọba APC to n ṣakoso nipinlẹ Ogun lakooko yii ti mu ifasẹyin ba eto ọrọ aje nipasẹ inakuna  ti wọn si ti lilo awọn ohun alumọni wa nilokulo.

O ni idunnu nla ni yoo jẹ fun ẹgbẹ wọn bi oludasilẹ Alternative ba le gba lati darapọ mọ wọn, pẹlu ileri pe awọn yoo gba rukutu tii.

Ninu ọrọ Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi lo ti kọkọ dupẹ lọwọ ẹgbẹ naa pe wọn fi ohun rere lọ oun.

O gboriyin fun ẹgbẹ oṣelu Labour fawọn ipa ti wọn ti ko sẹyin paapaa oludije wọn fun ipo aarẹ, Peter Obi, fun bo ṣe igberu ba ẹgbẹ naa lorileede yii.

Bẹẹ lo sọ nipa ipinnu ọkan ẹ lati le jẹ ki ipinlẹ Ogun tubọ gberu sii nipasẹ idagbasoke lori ọrọ aje.

Ṣowunmi tun sọ pe oun dupẹ lọwọ wọn fun oore ọfẹ ti wọn fẹẹ foun lati dije fun ipo gomina,amọ ki wọn foun laaye lati le ronu sii, nitori o gba ero pupọ.

Bakan naa lo tun mẹnuba iṣoro oju ọna tawọn eeyan n koju, to si rọ ijọba Dapọ Abiọdun lati tubọ wa nnkan ṣe, bo tilẹ jẹ pe o sọ pe wọn gbiyanju nnkan ti wọn le ṣe, amọ ko tii to. 

Ṣugbọn ṣa o, o sọ pe ko to di pe oun fun wọn lesi nnkan ti wọn ba wa, oun gbọdọ fi to awọn mẹta kan leti lati le tẹsiwaju.

Awọn naa ni Aarẹ Bọla Tinubu atawọn meji ti wọn ti jẹ aarẹ lorileede yii ri.

No comments:

Post a Comment

Pages