Awọn ọlọpaa ti n gbena woju awọn ibalopọ laarin ọkunrin si ọkunrin ati obinrin si obinrin - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday, 2 December 2025

Awọn ọlọpaa ti n gbena woju awọn ibalopọ laarin ọkunrin si ọkunrin ati obinrin si obinrin

Kekere kọ lawọn ọlọpaa ti wọn parapọ nilẹ Yoruba fi n doju ija kọ awọn ọbayejẹ ti wọn sọ ibalopọ laarin ọkunrin si ọkunrin ati obinrin si obinrin di aṣa lawujọ, ni bayii, ọwọ ti tẹ awọn kan, nigba ti wọn si n wa awọn afurasi mii ti wọn ti sa l

Gẹgẹ bi iwadii oniroyin wa, laipẹ yii lawọn ọlọpaa yi yawọ ile ijo meji kan ọkan niluu Eko ati ikeji ni Oṣogbo nibi tawọn afurasi ọhun ti gbadun ara wọn.

Iwadii fi ye wa pe ile ijo kan to gbafẹ lagbegbe Abule Ẹgba ati eyi to wa laduugbo Ayegbami,Iwoye niluu Oṣogbo lawọn ọlọpaa ọhun ti ya lu wọn.

Bi wọn ṣe rawọn ọlọpaa yii lawọn eeyan naa fẹẹ ma sa lọ, amọ tọwọ tẹ ọpọ ninu wọn.

Afurasi mẹrinla lọwọ tẹ ninu wọn, ti wọn si ko wọn lọ si oluuleṣe ọlọpaa ni Eko, nibi ti wọn ti jẹwọ pe loooto lawọn maa n ba ara wọn lopọ ati pe awọn lẹgbẹ ti wọn da silẹ pẹlu.

Bo tilẹ jẹ pe mẹsan an ninu wọn lọwọ kọkọ tẹ, ko to di wọn tun mu awọn marun un mii lakoko ti iwadi wọn n lọ lọwọ.

Bẹẹ la tun gbọ pe igbakeji ọga ọlọpaa pata lorileede yii niluu Eko tun ti n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọlọpaa to wa nilẹ Ibo lati rii pe ọwọ tẹ awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ LGBTQ, ti wọn sapamọ si agbegbe ibẹ awọn naa ni Abioye Yetunde Jumọkẹ, Ahmed Bada, Samuel Dino Robinson, Bukọla Ọlalekan , Raufu Olufunmilayọ, Haruna Balikis, Oluṣegun Ọdẹjimi, Kẹmi Rachael Akinde, Onyenwe Chidinma Jennifer, Adebọwale Adeyẹmi Abiọla Ọlasunbo Wuraọla, Adegunwa Fọlaṣade (F), ati Adeegbe Ọlaoluwa Sunday atawọn miii pẹlu.

Bakan naa la gbọ pe awọn miii ninu wọn ti fi orileede yii silẹ sa lọ si oke okun. Lara wọn ni Samuel Dino Robinson, Abioye Yetunde Jumọkẹ, Ahmed Bada, Adegunwa Folashade, Adeegbe Olaoluwa Sunday, Kemi Rachael Akinde , Raufu funmilayo and Olasunbo Wuraola.

Ileeṣẹ ọlọpaa ajumọṣe ọhun nilẹ Yoruba ti wa sọ pe awọn ti gbe igbesẹ lati rii pe gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti wọn ṣa lọ lọwọ yoo ba tawọn yoo si fi wọn jofin.

No comments:

Post a Comment

Pages