Apero Ẹgba iyẹn'Egba Summit' yoo tubọ ni ilọsiwaju lakooko temi- Dokita Gbenga Adeoye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 20 December 2025

Apero Ẹgba iyẹn'Egba Summit' yoo tubọ ni ilọsiwaju lakooko temi- Dokita Gbenga Adeoye



Aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan fun Ẹgba Summit, Dokita Gbenga Adeoye, ti ṣeleri pe idagbasoke ati ilọsiwaju yoo tubọ de ba ẹgbẹ wọn ati pe oun ko ni rẹwẹsi lati sa gbogbo ipa oun.

Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n ka ọrọ mo tẹwọgba ipo tuntun ti wọn yan sii gẹgẹ bi aarẹ.

Lara awọn erongba meje to ni lọkan fawọn eeyan ẹ to fi to wọn leti ni lati ṣe ẹrọ igbalode ti yoo ni akọsilẹ, eyi ti yoo jẹ ki gbogbo ọmọ Ẹgba lapapọ mọ bo ṣe n lọ.

Lati jẹ ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ yala ti wọn ti wa nibẹ ati tuntun wa ni isọkan, ki ajọṣepọ to danmọnran wa laarin wọn.

Bakan naa ni aarẹ tuntun ẹgbẹ ọhun tun sọ pe lara erongba oun ni lati wa ọna bi awọn okoowo ati iṣẹ akanṣe yoo ṣe maa wọlu Ẹgba.

O ni itọni awọn ọdọ tawọn naa yoo di aṣiwaju lọjọ iwaju tun jẹ oun logun. O lawọn yoo tun maa ṣe idalẹkọọ ati iranlọwọ fawọn olokoowo kekekee.

Gbogbo ọna lo sọ pe oun yoo wa lati ṣatilẹyin fun ileewe giga yunifasiti tijọba apapọ ẹkọṣẹ ogun ati sayẹnsi  lati ko lọ sori ilẹ wọn patapata pẹlu kikọ gbọngan ikẹkọọ  atawọn ohun elo ti yoo wulo fun wọn.

Panbabari ẹ ni  wiwa ọna tawọn eeyan kanka lawujọ yoo fi darapọ mọ wọn.
Ninu ọrọ Oloye Taiwo Adeoluwa, to jẹ alaga igbimọ awọn alakoso ẹgbẹ naa, o rọ aarẹ ẹgbẹ tuntun ọhun lati wa ti yoo fi so gbogbo ọmọ ẹgbẹ pọ, lati le wa ni isọkan.

Bẹẹ lo tun dupẹ lọwọ Oloye Tokunbọ Ọdẹbunmi to jẹ aarẹ ẹgbẹ ọhun fun ayẹyẹ igbalejo wọn.

Dokita Gbenga Adeoye lo ti kọkọ jẹ igbakeji aarẹ fun bi ọdun meji, ko to depo aarẹ, ti yoo si tun lo ọdun meji pẹlu.

No comments:

Post a Comment

Pages