Wọ́n ni APC lápapọ̀ ní káwọn ọmọ ẹgbẹ́ ma bà á Gbenga Daniel ṣe e pọ̀ mọ́-Irọ́ ni wọ́n pa o-Akọwe iroyin Daniel - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 6 November 2025

Wọ́n ni APC lápapọ̀ ní káwọn ọmọ ẹgbẹ́ ma bà á Gbenga Daniel ṣe e pọ̀ mọ́-Irọ́ ni wọ́n pa o-Akọwe iroyin Daniel


Ṣe ni  wahala to n waye laari Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun ati Sẹnetọ Gbenga Daniel, to n ṣoju ẹkun Ogun East, nile igbimọ aṣofin niluu Abuja, tun gbọna mii in yọ nigba ti wọn kede pe awọn  oloye ẹgbẹ APC, niluu ABbuja ti ọwọ si yiyọ Gbenga Dsniel pats ninu ẹgbẹ naa.

Bẹẹ ni wọn tun sọ fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ pe kiwọn ma ba a ni nnkankan papọ mọ.
Gẹgẹ bi atẹjade ti akọwe iroyin Gomina Dapọ Abiọdun, Ọgbẹni Lekan Adeniran fi sọwọ si wa lọsan ana,lo ti ṣalaye igbesẹ naa waye lori lẹta kan ti alaga ẹgbẹ APC, Oloye Yẹmi Sanusi ati akọwe ẹ, Tẹlla Aderibigbe  kọ si alaga ẹgbẹ naa lapapọ, lọjọ kẹta, oṣu kẹwaa, ọdun yii pe pẹl bawọnṣe da Gbenga Daniel duro sibẹ ko yipada ninu ẹsun ti wọn fi kan an.

Gẹgẹ bo ṣe  wi,ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii ni egbe APC,ti kọkọ kede pe awọn da a duto ninu ẹgbẹ naa bi ilana ati ofin ẹgbẹ wọn ṣe sọ fawọn aṣemaṣe ti wọn lo n ṣe

Atẹjade naa sọ pe  awọn rọ ijọba, ẹlẹgbẹjẹgbẹ ki wọn ma ṣe ba Daniel ṣe pọ mọ gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ nitori ki i ṣe ara wọn mọ.

Ṣugbọn ni bayii, akọwe iroyin Sẹnetọ Gbenga Daniel, Steeve Oniyide, ti sọ pe otubantẹ lọrọ naa, nitori awọn ti wọn gbe atẹjade naa ko fẹsẹ ẹ rinlẹ to

O sọ pe ki wọn mu lẹta ti alaga apapọ ẹgbẹ naa ti fọwọ si yiyọ Dnie gẹgéẹ bi ọmọ ẹgbẹ.

Ati pe  ohun tawọn ṣewadii le lori ni pe ṣe ni akọwe iroyin Gomina ọhun kan gbeigbeugbe jade, awọn ko mọ  igba to n gba iṣe ẹgbẹ ṣe.

O ni ko le ya awọn lẹnu nitori nnkan tawọn gbọ ni pe o tipẹ ti wọn ti n yọ awọn oloye ẹgbẹ nipinlẹ Ogun lẹnu ti wọn si tun dunkoko mọ wọn pe ki wọn gbe igbesẹ kia lori ọrọ Dsniel.

O ni nigba ti wọn ko ri nnkankan ni wọn lo awọn ọmọọṣẹ Gomina lati gbe atẹjade nas sita, o ni digbi ni Sẹnetọ Gbenga Daniel ṣi wa ni APC ipinlẹ Ogun.

No comments:

Post a Comment

Pages