Níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ANTP:Àwọn àgbà òṣèré fi ìdùnnú wọn hàn lórí àṣeyọrí ẹgbẹ́ nàá - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday, 3 November 2025

Níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ANTP:Àwọn àgbà òṣèré fi ìdùnnú wọn hàn lórí àṣeyọrí ẹgbẹ́ nàá



Awọn agba bọ wọn ni bi inu ẹni ba dun, a ki i pamọra bẹẹ lọrọ ri fawọn agba ẹgbẹ oṣere tiata ANTP, nigba ti wọn gboṣuba fawọn oloye ẹgbẹ ọhun fawọn aṣeyọri nla ti wọn ti mu ba wọn latigba ti wọn ti ṣakoso bi ọdun meji sẹyin.

Nibi ayẹyẹ idanilẹkọọ apero ẹlẹẹkeji iru ẹ to waye niluu Ibadan lọsẹ to kọja ni wọn ti n kan sara si wọn fawọn ipa ribiribi ti wọn ti ko.

Bo tilẹ jẹ pe Oloye Yẹmi Elebuibon ko le wa nitori irinjo wọn lọ si oke okun sibẹ wọn ranṣẹ, nibi ti wọn ti rọ awọn ọmọ ẹgbẹ lati tẹsiwaju ki wọn ma ṣe rẹwẹsi ọkan lori ohun gbogbo ti wọn ṣe.

Bẹẹ ni Oloye Lere Paimọ tọpọ mọ si Ẹda onileọla, ti wọn fi ijokoo yẹ won si lọjọ naa fi idunnu ẹ han lori bi ogo ẹgbẹ naa ṣe tun pada yọ ju ti atẹyinwa.

O waa gba wọn lamọran lati tubọ fun ifẹ laaye laarin wọn, ki wọn ma si gba ede aiyede laaye.

Lara awọn to wa da wọn lẹkọọ lọjọ naa ni  gbajumọ oṣere nni Dokita Afeez Oyetoro, tọpọ mọ si Saka, nibi to ti sọrọ lori bi
 a ṣe le dangajia nip-a ere itage ati fiimu.

Nibẹ lo ti kọkọ mẹnuba ere ori itage ati fiimu, bi wọn ṣe le jẹ oṣere, atawọn nnkan mii-ii.

Nigba ti Ambasedọ, Ọjọgbọn A B S Akande da wọn lẹkọọ lori isuna owo ati aleebu ti wọn ba fẹẹ gbe ere jade. 

Arẹ Akọgun Tai Arogunmatidi, ipenija to wa lori yiya aworan lakooko ti wọn ba wa ni lokeṣan.
Pambabari ọjọ naa ni ti ifilọlẹ kaadi idanimọ igbalode ti wọn ṣe lọjọ naa, aarẹ ẹgbẹ ọhun Dokita Rasak Ọyadiran tọpọ mọ si Baroka lo ṣi aṣọ loju eegun. Nigba ti Oloye Lere Paimọ jẹ ẹni akọkọ ti wọn gbe sii lọrun.


No comments:

Post a Comment

Pages