Ileeṣẹ IHS ṣagbekalẹ idanilẹkọọ fawọn ọgọrun-un oniroyin nipinlẹ Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday, 3 November 2025

Ileeṣẹ IHS ṣagbekalẹ idanilẹkọọ fawọn ọgọrun-un oniroyin nipinlẹ Ogun

Fun ọjọ meji gbako lawọn oniroyin bii ọgọrun-un ko ara wọn jọ papọ si gbọngan kan ti wa nileetura AA Entertainment and Tourism, eyi ti wọn n pe ni Park Inn tẹlẹ, ni Kutọ niluu Abẹokuta, nibi ti wọn ti fi imọ kun imọ wọn lori iṣẹ ti wọn yan laayo.

Ko si deede ribẹ bi ko ṣe idanilẹkọọ ti Ileeṣẹ to n ri sọrọ riri awọn opo ileeṣẹ ikansira-ẹni (mast) kaakiri agbaye, IHS, to wa lorileede Naijiria ṣagbatẹru ẹ.

 Ẹgbẹ awọn aṣoju-kọroyin (Correspondents' Chapel) nipinlẹ naa ni a gbọ pe o ṣatọna bawọn oniroyin yooku
ṣe jẹ anfaani rẹ.

Nibẹ ni awọn agbaagba lẹka eto iṣẹ iroyin nilẹ Naijiria, to fi mọ ijọba ipinlẹ Ogun ti fi idunnu wọn han si agbekalẹ eto ọhun, ti wọn jẹ ko di mimọ nipa pataki idanilẹkọọ atigbadegba fawọn akọroyin, lati le mọ awọn ofin to de wọn.

Nigba to n sọrọ, Arabinrin Yẹmisi Diya-Salawu, to jẹ alabojuto ọrọ ofin nileeṣẹ IHS Nigeria ṣalaye lẹkunrẹrẹ lori ifarajin wọn lati maa ro awọn eeyan lagbara.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe ipa to jọju ni awọn akọroyin n ko ninu idagbasoke ilẹ Naijiria, nipa jijẹ ki araalu mọ ohun to n lọ, leyi to n ṣe iranwọ nla fun itẹsiwaju.

O loun to ṣe pataki fun wọn ni lati ro awọn akọroyin lagbara nipa imọ ati awọn ohun ti yoo jẹ ki iṣẹ wọn tayọ yatọ, to si loun nigbagbọ pe idanilẹkọọ naa yoo tun jẹ ki awọn akọroyin ni imọ kikun nipa ojuṣe wọn.

“A ni ireti wi pe idanilẹkọọ naa yoo fun awọn akọroyin to n ṣiṣẹ nipinlẹ Ogun ni koriya, lati jẹ ki wọn jẹ akọṣẹmọṣẹ ati ọjọgbọn nidi iṣẹ ti wọn yan laayo, ki iṣẹ wọn le kẹsẹ," Diya-Salawu sọ bẹẹ.

Oludamọran pataki fun gomina lori eto iroyin, Ọnarebu Kayọde Akinmade to ṣoju Gomina Dapọ Abiọdun ati akọwe ijọba, Ọgbẹni Tokunbọ Talabi nigba to n fi idanilẹkọọ lelẹ jẹ ko di mimọ pe o ṣe pataki ki ijọba ni ibasepọ to dan mọnran pẹlu awọn akọroyin, leyi ti yoo mu idagbasoke wa.

Akinmade sọ pe ipa ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin lawọn akọroyin n ko ninu ijọba ati ilọsiwaju orile-ede, ti awọn si gbọdọ maa lu wọn lọgọ-ẹnu.

Bakan naa lo tọka si awọn iṣoro ti awọn akọroyin n dojukọ lorile-ede Naijiria, lara rẹ si ni aini anfaani si iroyin kikun, ifiyajẹni lọna aitọ, aika wọn si ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O wa gbe oṣuba kare fawọn ẹgbẹ aṣoju-kọroyin to ṣagbekalẹ eto naa ti ileeṣẹ IHS Nigeria ṣagbatẹru rẹ, to si ni anfaani tuntun ni yoo jẹ wi pe pupọ ni yoo tun ni imọ ati iriri tuntun.

Nigba to n sọrọ, alaga ẹgbẹ aṣoju-kọroyin nipinlẹ naa to ṣagbekalẹ eto ọhun, Kọmureedi Razaq Ayinla, ẹni to tun jẹ akọṣẹmọṣẹ agbẹjọro sọ pe oniruuru adojukọ ni awọn ọmọ ẹgbẹ wọn n dojukọ lorileede Naijiria, to si di dandan ki awọn ṣe idanilẹkọọ naa lati le mọ ọna abayọ.

O dupẹ lọwọ awọn alakoso ileeṣẹ IHS Nigeria, awọn oludanilẹkọọ ati awọn akopa fun atilẹyin wọn lati rii pe eto naa waye.

Ninu ọrọ tirẹ, Olu Orile-Ilawo nipinlẹ Ogun, Ọba Alexander Oluṣẹgun MacGregor fi idunnu rẹ han si awọn akọroyin, to si loun to ṣe pataki ni araalu maa bu ọla ati iyi fun wọn lori ipa ti wọn n ko.

Ọba alaye naa ni, bo tilẹ jẹ pe oun ko yan iṣẹ naa to jẹ iṣẹ baba oun laayo, sibẹ o sọ pe iṣẹ akọroyin lo sọ baba oun, Oloogbe Bisi MacGregor di ọlọla, pẹlu bi awọn oyinbo ṣe fun un lanfaani lati jẹ alagbata ẹja nilẹ Naijiria lọdun naa.

Ọgbẹni Lẹkan Otufọdunrin ti figba kan ri jẹ olootu iwe iroyin The Nation, ati Ọjọgbọn Dele Ọdunlami to jẹ ọkan lara awọn agba ni fasiti Ọlabisi Ọnabanjọ, ẹni ti Ọmọwe Fọlarin Jamiu ni fasiti Crescent gba ẹnu rẹ sọrọ ni wọn ṣe idanilẹkọọ naa, ti wọn si sọ iṣoro ati awọn ọna abayọ lori iṣẹ akọroyin nilẹ Naijiria ati lagbaye.

No comments:

Post a Comment

Pages