Ìjà ìlara ni Dàpọ̀ Abíọ́dún bá Gbenga Daniel jà- Steeve Oliyide - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday, 11 November 2025

Ìjà ìlara ni Dàpọ̀ Abíọ́dún bá Gbenga Daniel jà- Steeve Oliyide



Steeve Oliyide, to jẹ akọwe iroyin fun Aṣofin Gbenga Daniel, ton ṣoju ẹkun agbegbe Ogun East, nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja, ti sapejuwe ohun to waye laaarin ọga ẹ ati Gomina Dapọ Abiọdun gẹgẹ bi ilara.

O sọrọ yii nibi ipade agbaye tawọn ọmọ lẹyin Aṣofin Gbenga Daniel pe, eyi to waye ni gbọngan Asọludẹrọ, to wa niluu Ṣagamu.

Nibẹ lawọn agba ẹgbẹ oṣelu APC ni Ogun East tun ti sọ pe ala ti ko  le ṣẹ ni erongba awọn kan lati da Aṣofin naa duro ninu ẹgbẹ ọhun.

Steeve Oliyide tun sọ pe ẹdun ọkan lo n jẹ fawọn nitori bijọba ipinlẹ Ogun, ṣe fẹẹ ma gbaṣẹ ẹgbẹ ṣe, to ni ko yẹ ko ri bẹẹ.

O sọ pe ninu oṣu kẹjọ ọdun yii ni wọn ti kọkọ gbero ẹ nigba tawọn ri ka lori ẹrọ ayelujara ibanidọrẹ to jẹ ti ẹnikan to pe ara  ẹ ni alakoso olupolongo ẹgbẹ, ipo ti ko han si ọmọ ẹgbẹ kankan lakooko igba naa.

O ni " Njẹ o dun gbọ leti pe ori ẹrọ ayelujara ni wọn yoo ti kede iru nnkan bẹẹ, ki i ṣe pe wọn gbe iwadii kankan kalẹ, bẹẹ ni wọn ko kọwe ifẹsun kan, bẹẹ ni wọn ko kọwe idaduro, ẹ gbọ, nibo ni wọn ti n ṣe iru nnkan bẹẹ"

Oliyide ṣalaye pe laisi gbogbo awọn ẹri yii sibẹ, ṣe lawọn oniroyin kan tun gbe e jade lai wadii okodoro ọrọ.

Ọkunrin yii wa mẹnuba hulẹhulẹ wahala to  n waye laarin Gbenga Daniel ati Dapọ Abiọdun,o ni ibo sẹnetọ fẹkun Ogun East, fọdun 2027.

O ni bawọn to sunmọ Gomina Abiọdun ṣe n wọna lati yọ ọwọ Aṣofin Daniel lawo lati ma ṣe dije lẹẹkeji.

O sọ pe lati ọdun 2019, ,ni ija ilara yii ti bẹrẹ pẹlu bi Daniel ṣe tiraka pẹlu awọn eeyan ẹ lati jẹ ki Abiọdun wọle fun ipo gomina nigba naa.

Oliyide ni, 'Lọdun 2023, Abiọdun tun jawe olubori pẹlu ibo ẹgbẹrun mẹrinla, o din diẹ, ijọba ibilẹ meje ninu mẹsan lo ti lulẹ ni Ogun East, to fi mọ wọọdu ati ijọba ibilẹ ẹ amọ ti Daniel jawe olubori pẹlu ami ibo gbọgbọrọ iyẹn 115,147.

Bẹẹ lọkunrin yii tun mẹnuba gbogbo igbesẹ wọn lati wole ati ọfiisi ti Daniel kọ, eyi tijọba Abiọdun sọ pe ko ṣe awọn nnkan to yẹ ko ṣe.

Awọn agba ẹgbẹ naa wa rọ awọn agba ẹgbẹ lapapọ lati tete gbe igbesẹ lori iwa lati da wahala silẹ ninu APC Ogun tijọba to wa lode rawọ le.

Lara awọn to wa nibẹ ti wọn fọwọ si iwe ti Steeve Oliyide ka ni Ọgagun Olumuyiwa Okunọwọ ,
Giwa Niyi Osoba, Ọtunba Korede Okusanya,
Ronke Oduneye,Arẹmọ Babatunde Adesanya, Josephine Makanjuola,
Dokita Bankọle Osisanya, Wọle Olubẹna,
Abiodun Adesanya,Dele Ọsifade, ati
Alaaja Ganiyat Busari.

No comments:

Post a Comment

Pages