Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kọkanla, ọdun yii ni bẹbẹ yoo tun bẹ latọdọ gbajumọ sọrọsọrọ nni, Kọlawọle Adejojo, tọpọ mọ si Kasnaty Sugar, nigba ti yoo tun gbe awo orin agba onifuji kan, Ọmọbọlaji Ajani tinagijẹ ẹ n jẹ Easy Kabaka jade.
Gẹgẹ bi ariwo to n jade kaakiri igboro, Microphone Mi Da, MMD, ni akọle orin ọhun, eyi tawọn araalu ti n reti lati gbọ orin tuntun ọhun.
Bi ẹ ko ba mọ, ọkan lara awọn agba ọjẹ onifuji ni Easy Kabaka tawọn naa si ti fi igba kan lo igba ri.
Ṣugbọn ṣadeede lawọn eeyan ko gbọ nipa irawọ oṣere olorin fuji ọhun mọ koda awọn eeyan ko mọ pe Easy Kabaka si wa laye.
Ko to di pe Kọlawọle Adejojo ṣawari ẹ lori eto ẹ kan Alangere nibi to ti maa n gbe awọn onifuji tawọn eeyan ti gbagbe, ti wọn ko gburo mọ sita.
Ori eto Kasnaty yii lawọn eeyan tun ti gbọ nipa ọkunrin onifuji yii nibi to ti pariwo sita pe oun ko ku o ṣibẹ orin ṣi wa lọpọlọ ẹ atawọn iriri ẹ sẹyin nidi iṣẹ fuji.
A o ranti pe bi oṣu meloo kan ṣẹyin ni Kasnati ti kọkọ gbe orin agba onifuji kan Mọrufu Tọlani, tọpọ mọ si Mọrufu Ebi jade, ti akọle ẹ jẹ FLF.
No comments:
Post a Comment