Aṣofin Gbenga Daniel to n ṣoju agbegbe Ogun East nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja ti dupẹ lọwọ Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, lori bo ṣe fọwọ si ibudo fawọn oloogun oju omi atawọn iṣẹ akanṣe mii-ii ṣagbegbe ijọba ibilẹ Ogun Waterside, eyi to ṣapejuwe pe yoo tun ran eto ọrọ aje ati aabo lọwọ.
O sọrọ yii lakooko to gbe abẹwo to fi sọri Bọla Ahmed Tinubu/Ọtunba Gbenga Daniel iyen BAT/OGD,de ijọba ibilẹ Ogun Waterside, eyi to waye ni Abigi, lọjọ Aiku, Sannde yii.
Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun naa tun gboriyin fun Tinubu fun atilẹyin ẹ lori iṣẹ akanṣe ibodọkọ fawọn ologun oju omi, eyi ti wọn ṣe lọwọ ni Ọlọkọda, nijọba ibilẹ ọhun to ni yoo mu iparere ba ọrọ aje pẹlu.
O fi idunnu ẹ lori bijọba apapọ ṣe dide lati ṣatunṣe ọna to lọ lati ijọba ibilẹ naa ti yoo maa gba Eko si Kalaba.
Aṣofin naa wa sakiyesi pe ipinnu rere ni Aarẹ Tinubu ni fun orileede yii ati pe erongba iṣakoso ẹ ni lati ro awọn araalu lagbara nipasẹ awọn iṣẹ akanṣe.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ibudo oloogun ti wọn n kọ si Ode-Omi,yoo tun jẹ ki ọrọ aje burẹkẹ, ti yoo tun pese iṣẹ fawọn eeyan ilu atawọn idagbasoke imayedẹrun.
Daniel waa sọ pe inu gbogbo awọn ara ipinlẹ Ogun lo dun lori akitiyan rere ti Tinubu ti mu ba wọn, eyi to si fi wọn lọkanbalẹ lati dibo fun un lẹẹkeji gẹgẹ aarẹ orileede yii.
Daniel sọ pe" Mo nigbagbọ pe Ọlọrun fẹran wa nijọba ibilẹ yii, nitori ẹ lo ṣe fun wa laaye ẹlẹẹkeji lati mu erongba wa ṣẹ, lati bii aadọta ọdun sẹyin nilẹ yii ti wa fawọn oloogun oju omi, amọ ti Ọlọrun sọ pe akoko emi Sẹnetọ Gbenga Daniel, ni yoo di mimuṣẹ.
No comments:
Post a Comment