Awọn araalu Sango ọta ṣadura fun Ọmọọba Olusanjọ Olurebi fun ayẹwo oju ati gilasi ọfẹ to fun wọn. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 12 November 2025

Awọn araalu Sango ọta ṣadura fun Ọmọọba Olusanjọ Olurebi fun ayẹwo oju ati gilasi ọfẹ to fun wọn.

Awọn agba bọ, wọn ni oju ni imọlẹ, idi niyi ti wọn fi maa n gbadura pe ki adaniwaye ma sọ wa si okunkun aye.

Lọjọọru, Wẹsidee, ni ajọ nla kan ti wọn pe ni Ọmọọba Sanjọ Olurebi ṣagbatẹru ayẹwo oju ati gbigba gilaasi oju lọfẹẹ, eyi to waye Jọju, Sango, nijọba ibilẹ Ado Odo Ọta nipinlẹ Ogun.

Nibi eto to waye ọhun lawọn araalu to fi mọ awọn ara ọja ti jade sita lati wa ṣe ayẹwo oju wọn.

Nibi to ka awọn to kopa nibi eto ọhun lara to lati nnkan bii aago mẹjọ aarọ lawọn eeyan ti n debẹ nigba ti yoo si fi to aago mọkanla, o ti kun fọnfọn.
Nigba to n sọrọ nipa idi ti wọn fi ṣeto ọhun, Ọnarebu Bello Abiọla Ọlatunji Isiaq, o sọ pe ilu Sango jẹ eyi tawọn ti ṣalaini awọn ohun elo awujọ, nitori aini awọn aṣaaju rere.

O ni bi wọn ṣe n dojukọ awọn ileeṣẹ to wa nibẹ ti pọju. Ijọba ibilẹ Ado odo Ọta lo ni  o jẹ eyi tileeṣẹ nla pọ si ni orileede yii, lẹyin naa lo ni o kan Ikẹja, nipinlẹ Eko.

Ọnarebu Abiọla Isiaq tun sọ pe pẹlu bawọn ileeṣẹ nlanla ṣe pọ to ẹdun ọkan lo jẹ pe awọn ara Ado Odo Ọta ko jẹ anfaani ẹ, nitori igbe aye tọpọ n gbe nipasẹ aito ilera.
O ni " Pẹlu iwaadi ta a ṣe lati mọ pe iṣoro oju bawọn eeyan finra, awa taa jẹ ajọ Ọmọọba Olurebi, awọn eeyan ba wa sọrọ, pe ka ba wọn wa nnkan ṣe lori ọrọ iṣoro oju. Idi niyii ta a fi ṣagbekalẹ ẹ niyẹn" 

Ọkunrin yii tun sọ pe igba akọkọ kọ ree tawọn yoo ṣeto ayẹwo oju latọdọ ajọ ọhun, o lawọn ti kọkọ ṣe ni aafin Ọlọta, nibẹrẹ oṣu yii.

Bẹẹ lo sọ pe awọn yoo tun ṣe irufẹ iru ẹ kaakiri. O lẹyin eleyii ajọ naa tun ti fawọn ọmọleewe ni iwe lawọn ileewe alakọbẹrẹ mẹrin ni agbegbe Sango yii.

Nigba to n ṣapejuwe Ọmọọba Sanjọ Olurebi, ẹni to ṣonigbọwọ eto ọhun, ẹni to n gbe ni oke okun, o sọ pe ẹlẹyinju aanu ni, ti ko gbagbe awọn eeyan tiẹ.

O ni ọkunrin naa ni Aṣiwaju awujọ Ẹgba ni Machester, loke okun ati pe Alake tilẹ Ẹgba lo fi jẹ lakooko naa iyẹn lọdun 2012.

O ni gbogbo eeyan lo n ṣe fun lọna to le fi san oore fun awujọ to to wa. O ni awọn ọgọfa ni wọn kopa nibi ayẹwo oju lọfẹẹ naa, ti wọn si mu digi lọ sile.

Ninu ọrọ lara awọn to jẹ anfaani nibi eto ọhun Ọgbẹni Bello Yusuf, to n gbe lagbegbe Sango, fi idunnu ẹ han lori bi wọn ṣe fun un ni gilasi oju, lẹyin ti wọn ṣe ayẹwo fun un.

O sọ pe oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe oun lanfaani lati le gba gilaasi, o tun waa fẹmi imoore ẹ han si onigbọwọ eto ọhun.


No comments:

Post a Comment

Pages