Ẹgbẹ oṣelu ADC nikan ni ọkọ igbala fọdun 2027- Salvador - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 25 October 2025

Ẹgbẹ oṣelu ADC nikan ni ọkọ igbala fọdun 2027- Salvador

 
Agba oṣelu nni to tun jẹ oludasilẹ fẹgbẹ 'Conscience Forum" Ọnarebu Moshood Adegoke Salvador, ti sọ pe ẹgbẹ oṣelu ADC, nikan ni ọkọ igbala ti yoo mu awọn ọmọ orileede yii de ebute ofo.

Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko toun atawọn eeyan ẹ ti wọn jọ wa ni Conscience Forum darapọ mọ ADC, tipinlẹ Eko, eyi to waye lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii.

O sọ pe awọn darapọ mọ ẹgbẹ ọhun nitori oun nikan lawọn gba pe o le mu atubọtan rere ba ẹgbẹ yii, ti wọn si le mu ayipada rere ba Naijiria.

O fikun ọrọ ẹ pe oṣelu to ni ẹri ọkan lawọn ki i ṣẹ ẹtanu nitori ẹ lawọn ṣe gbọdọ ko ara wọn nijanu, nitori awọn mọ pe awọn ko le padannu.

Salvador tun ṣalaye siwaju pe, "A ko le padannu ninu oṣelu yii, a si ti ṣetan lati fopin si oṣelu imọtara ẹni, ki a gba iṣọkan ati alaafia laaye"

Bakan naa lo rọ awọn ọmọ Ibo to wa laarin wọn lati jọ ṣiṣẹ pọ ki alaafia le jọba ati
 pe ẹgbẹ ADC, ki i ṣẹgbẹ ẹlẹyamẹya bi ko ṣe ti ajumọṣe.

O waa ni awọn ti lo akoko naa lati kede faye pe Conscience Forum, ti darapọ mọ ADC.

Bẹẹ lo rọ awọn ọmọ ẹgbẹ ki wọn bẹrẹ si nii lọ gba kaadi ọmọ ẹgbẹ niwọngba ti wọn ba ti ko lọ si wọọdu wọn, o ni eyi ṣe pataki ju.

Nigba to n sọrọ, to n fi n ki wọn kaabọ sinu ẹgbẹ ADC, alaga wọn nipinlẹ Eko, George Ashiru, mu da wọn loju pe pẹlu ifẹ lawọn fi gba wọn sinu ẹgbẹ lati le jọ ṣiṣẹ pọ.

O sọ pe ibukun nla ati oriire ni idarapọ Conscience Forum jẹ fun ADC, tawọn si ti gba wọn tọwọ tẹsẹ.

O waa sọ lọjọ naa pe ko si iyapa ninu ADC, ati pe ọkan naa ni gbogbo wọn, ẹni to ba si ba iyapa wa, ko gba wọn lakooko lati lee danu.

Lara awọn to wa nibẹ lọjọ naa ni Arabinrin
 Naomi Abel Lassar, to jẹ olori awọn obinrin lapapọ. Dokita Bamidele Ajadi, igbakeji alaga lapapọ. Ọnarebu Debor, Nkem Ukandu;Duru Festus.
   

No comments:

Post a Comment

Pages