Ẹ jẹ́ kí n mú ìpínlẹ̀ ìjẹ̀bú wá, ẹ̀yin elénìní-- Sẹnetọ Gbénga Daniel - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 26 October 2025

Ẹ jẹ́ kí n mú ìpínlẹ̀ ìjẹ̀bú wá, ẹ̀yin elénìní-- Sẹnetọ Gbénga Daniel


Sẹnetọ Gbenga Daniel, to n ṣoju ẹkun Ogun East nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja, ti rọ awọn ti wọn ko fẹẹ ko mu ipinlẹ Ijẹbu wa, lati ma ṣe fi imọtara ẹni nikan ba nnkan ayọ yii jẹ,nitori o ka wọn kun elenini.

Ilu Iliṣan nijọba ibilẹ Ikẹnnẹ lo ti sọrọ  naa lakooko to n jabọ ibi to ṣẹ de fawọn to n ṣoju ẹ nile igbimọ aṣofin niluu Abuja.

O sọ pe kawọn araalu ma wo ariwo ọja nitori nnkan tawọn to fẹẹ  maa gba ẹyin bẹbọ jẹ yii yoo jẹ ni wọn wa.

Aṣofin Daniel tun sọ pe 'Ọlọrun lo ran mi wa, ti mo lẹsẹ kin in ni, ti mo tun lẹsẹ keji, emi ni wọn pe ni Arole Rẹmọ, emi naa si ni Ọbalọfin Ìjẹbu. Ni akokp ta a wa yii Ọlọrun fẹẹ ṣoore fun wa ni Ogun East, Ọlọrun ko nii jẹ ki eedi mu wa, taa ba gba lọtẹ yii, o digbere niyẹn"

" Nitori naa, ikilp ni mo n ṣe fun gbogbo wa, ẹ jẹ ki ori waa pe, ki ori wa fa epo, Ọlọrun lo mu akoko yiii wa lagbara Ọlọrun, a ṣe e ṣe fun wa"

Bakan naa lo mẹnuba awọni iṣẹ to ti ṣe to ti mu ọrọ aje gbooro si nilẹ Rẹmọ laraẹ nileewe Ṣapade ati papakọ ofurufu to  bẹrẹ ẹ kijọba tto wa lode yii pari ẹ.

Bẹẹ lo tun ran wọn leti nijọba ibilẹ naa bo ṣe ṣe pataki to lati ṣatilẹyin fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu lati wọle ẹlẹẹkeji lọdun 2027.

O aya aarẹ orileede yii, lati Ogun East lo ti wa nigba ti Tinubu funra ẹ jẹ ojulowo ọmọ Yoruba pọnbele, idi niyii tawọn fi gbọdọ ri pe o wọle ẹlẹẹkeji.

Daniel sọ pe lẹyin ti Aarẹ ba parii saa ẹlẹkeji ẹ, oun ni yoo ṣaaju wọn sọ ibi to ba kan.

 

No comments:

Post a Comment

Pages