Ẹsẹ o gbero nijọba ibilẹ Ado Odo Ọta nipinlẹ Ogun nigba ti wọn ṣayẹyẹ ifilọlẹ ẹgbẹ alatilẹyin fun Sẹnetọ Olamilekan Yayi lati di gomina lọdun 2027.
Eto ọhun to waye ni wọọdu kẹta ni wọn ti ṣafihan awọn oloye ẹgbẹ ti yoo maa ṣagbatẹru ẹgbẹ ọhun.
Ninu ọrọ Ọnarebu Lẹyẹ Ọdunjọ, to jẹ alakoso patapata fun ẹgbẹ naa lo ti dupẹ lọwọ awọn eeyan ijọba ibilẹ naa bi wọn ṣe tẹwọgba wọn fun ayẹyẹ to waye naa.
O sọ pe iṣẹ pataki to wa niwaju gbogbo wọn ni bi wọn yoo ṣe bẹrẹ itankalẹ bi Yayi yoo ṣe di gomina lọdun 2027.
O sọ pe gbogbo wọn lo ti rawọn iṣẹ takuntakun ti Sẹnetọ Ọlalekan Adeọla Yayi n ṣe lọwọlọwọ kaakiri ipinlẹ Ogun, eyi to ti mu inu awọn eeyan dun
Alakoso naa sọ pe akoko ti to fun wọn lati fẹnu ko ki Yewa Awori di gomina nipinlẹ Ogun nigba akọkọ, nnkan to sọ pe o le mu erongba wọn ṣẹ ni ki gbogbo wọn jọ fẹnu ko.
O waa sọ pe oun nigbagbọ pe Yayi ko nii doju ti wọn lẹyin to ba dori ipo ọhun.
Ninu ọrọ Ọnarebu Monsur Ọlawale Oloyede, ọkan lara awọn oloye ẹgbẹ lọjọ naa lo ti rọ awọn eeyan ti wọn ko ba ti ni kaadi idibo lati tete lọọ kopa nibi iforukọsilẹ to n lọ lọwọ.O sọ pe oun nikan ni wọn le lo lati fi dibo yan Sẹnetọ Ọlalekan Yayi wọle gẹgẹ bii gomina lọdun 2027.
No comments:
Post a Comment