Pẹlu orin ọpẹ ọlọkan-o-jọkan ati ijo ni wọn fi dupè lọwọ Aarẹ pe laipẹ yii ni ala wọn fun idasilẹ ipinlẹ naa.
Ninu ọrọ Sẹnetọ Gbenga Daniel, lo ti rọ awọn eeyan Ijẹbu pe kii ṣe akoko ti wọn wa yii lo yẹ ki wọn maa ba ara wọn ja, ki wọn jẹ ki nnkan ti wọn n wa tẹ wọn lọwọ na.
Bẹẹ lo tun sọ pe atilẹyin wọn fun Aarẹ Tinubu ṣi duro digbi fun ipadabọ ẹ ẹlẹẹkeji ninu ibo ti yoo waye lọdun 2027.
O sọ pe awọn nigbagbọ ati igboya ninu iṣejọba Tinubu gẹgẹ bi ilakaka ẹ lati jẹ ki ọrọ aje orileede tun gbẹnu soke ju bo ṣe wa yii lọ.
Daniel tun ṣalaye siwaju pe "Gẹgẹ bi ẹ ṣe yan mi bi aṣoju yin nile igbimọ aṣofin niluu Abuja, lara awọn iṣẹ mi ni lati mu awọn iṣẹ akanṣe wa sawọn agbegbe ti mo n ṣoju fun, ṣugbọn gbigbeṣẹ fawọn alagbaṣe ki i ṣiṣẹ mi, awọn ẹka to n ṣiṣẹ labẹ ijọba apapọ ni wọn wa fun"
O wa fi aidunnu ẹ sipo ti ọna Paddy Arikawe, to wa ni Ṣagamu tijọba ẹ ti ṣe lati nnkan bi ogun ọdun sẹyin wa ko bojumu,eyi ti wọn ko si ṣe atunṣe ẹ titi di akoko yii.
Bẹẹ lo mẹnuba lara aṣeyọri to de ba ijọba ibilẹ naa nipa bi Aarẹ Tinubu ṣe fọwọ si latigba akoso ileewe yunifasiti olukọni Tai Ṣolarin.
Bakan naa lo rọ ijọba ipinlẹ Ogun lati dide iranlọwọ fawọn eeyan ijọba ibilẹ Ijẹbu North-East lati ba wọn ṣatunṣe lori awọn ọna wọn to ti bajẹ.
No comments:
Post a Comment