Gẹgẹ bi iwe kan to ṣagbekalẹ ẹ ni ede oyinbo to pe ni ilana ba eto oṣelu orileede yii gẹgẹ bi opo fun ijọba tiwa-n-tiwa. igbesẹ fẹnikẹni to ba fẹẹ dupo oṣelu, ti gbọdọ jẹ ọmọ ẹgbẹ ti wọn forukọ ẹ silẹ laarin ọdun mẹrin ko to di pe ibo waye.
Sowunmi sọ pe igbesẹ yii gbọdọ jẹ atunṣe ofin ilẹ ẹka karundinlaaadọrun ati kẹtadinlaadọfa, kọkanlelaaadoje ati ikẹtadinlaadoje tọdun 1999. O ni yoo fopin si bi awọn oloṣelu kan se sọ ẹgbẹ oṣelu di irinajo afẹ, Ti ifẹ ọjọ iwaju ara wọn ju ti ilu lọ.
O ni akoko ti to lati fopin si iṣejọba isansa tawọn oloṣelu kan n ṣe ti wọn yoo kan ṣadeede fẹgbẹ oṣelu silẹ nitori imọtara ẹni nikan, ti ifẹ araalu ti wọn ṣoju fun ko si lọkan wọn.
Oludasilẹ 'The Alternative' wa sọ pe "A gbọdọ ṣayipada ifẹ ara ẹni ọṣelu ninu eto iṣejọba wa.Igbesẹ yii yoo tun wa fun ẹnikẹni to ba fẹgbẹ oṣelu ẹ silẹ lati padannu ipo to ba wa lakooko naa'
Labẹ eto yii lo ti ẹgbẹ oṣelu kọọkan yoo ti ni anfaati lati sagbekalẹ nnkan ti wọn n fẹ sinu iwe ofin wọn, ti wọn yoo si maa yan oludije to ku oju osuwọn,bẹẹ lo ni yoo fopin si baba isalẹ nidii oṣelu.
No comments:
Post a Comment