-Bẹẹ lọpọ awọn eeyan riṣẹ labẹ ẹ
Oriileede Canada ni Oluwafẹmi Ayeyẹmi ati iyawo ẹ n gbe tẹlẹ ti wọn ti n ṣiṣẹ oojọ wọn, ti Ọlọrun si gba fun wọn, ti owo n wọle deedee.
Ṣugbọn bi wọn ṣe n rowo to ko sigba kan ti wọn gbagbe ile ti wọn si maa n ranti pe ile ni abọ isinmi oko, ọjọ kan n bọ tawọn yoo filu ti wọn wa silẹ, ti wọn yoo pada silẹ baba wọn, gẹgẹ bi owe Yoruba kan to sọ pe aajo kii jin ki onile ma lọ sile.
Idi niyii ti wọn fi pamọpọ awọn yoo kọ ile itura ko siru ẹ ri lagbaaye si Naijiria, niluu abinibi wọn nibi, eyi yoo si maa pa owo fun wọn wale.
Wọn ko si jẹ ko falẹ ti wọn fi bẹrẹ si nii kọ si agbegbe kan niluu Ọbada, nikọja Abẹokuta, ti wọn si pe orukọ ẹ ni "FELIZA HOTEL"
Beeyan ba si de ibi ile itura ti wọn n kọ naa ko si ki wọn ki aje ku ikalẹ nitori owo ti wọn ti lori ẹ.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ko tii pari ẹ, ṣugbọn awọn ibi ti wọn ba iṣẹ de fihan pe erongba Olufẹmi ati iyawo ẹ lati sọ ootẹli ọhun di ti agbaye ko fi jayo pa, koda a tun le pe ni ọkan lara ile irinajo afẹ lagbaaye.
Nigba ti wọn ko awọn oniroyin lọ sabẹwo nibẹ, Olufẹmi, ọga agba ileeṣẹ naa sọ pe kekere nibi ti wọn si ba iṣẹ de lakooko yii ati pe to ba pari tan, yoo di ọkan pataki ile itura ti ko tii si lorileede yii.
O fikun ọrọ ẹ pe bi ile itura yii ba pari yoo di ohun iwulo lati gba alejo yala lorileede yii ati ni oke okun, fun isinmi tabi ṣayẹyẹ loorekoore.
O fikun ọrọ ẹ pe yoo tun jẹ ki ọrọ aje tun lọọ soke si, ti yoo maa mu ọpọ alejo wa ṣabẹwo.
Ayeyẹmi tun fi kun ọrọ ẹ pe ko si gbogbo nnkan ti wọn n fẹ nile itura to wa ni oke okun ti wọn ko nii pese ẹ.
Bẹẹ lo sọ pe yoo tun pese iṣẹ fawọn ọdọ bii ọgọrun ati ju bẹẹ lọ, tawọn naa yoo maa tipasẹ ẹ mọwọ lọ sẹnu.
O waa mu dawọn eeyan loju pe laipẹ yii ni wọn yoo pari iṣẹ ọhun ti yoo si di ohun elo.
No comments:
Post a Comment