Ẹgbẹ ilọsiwaju Ọmọluabi iyẹn Ọmọluabi Progresive ti pariwo sita pe gbogbo ọna lawọn kan fi n wa lati gba ẹmi akọwe tuntun fẹgbẹ oṣelu ADC, to tun jẹ Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹsọla, nitori oṣelu.
Gẹgẹ bi atẹjade kan Oluwaṣeun Abọsẹde to jẹ agbẹnusọ ati akọwe eleto fẹgbẹ naa fi sita jẹ ka mọ pe gbogbo nnkan to n waye lẹnu ọjọ mẹta yii nidii oṣelu ti fihan gbangba pe afaimọ ki wọn ma da ẹmi agba oṣelu naa lojiji.
Wọn lẹnu ọjọ mẹta yii lawọn n ri bi wọn ṣe n dunkoko mọ ẹni to ti figba kan jẹ minisita fọrọ abẹle eyi ti wọn ni ko yẹ ko ri bẹẹ ninu iṣejọba awarawa ta a wa yii.
Lọjọ kẹtalelogun, oṣu keje, ọdun yii ni wọn sọ pe Sunday Igboho, to jẹ ajijagbara fun ilẹ Yoruba ti kọkọ sọrọ kan sita pe "Ilẹ yoo mu wọn" eyi ti itumọ rẹ tumọ si lati doju ija Arẹgbẹṣọla.
Ẹgbẹ Ọmọluabi tun ṣalaye siwaju pe "Bakan naa lọjọ keji, oṣu kẹjọ ni iru idunkoko mii tun waye nigba ti Mayor Akinpẹlu, to jẹ agba oniroyin nibi to ti sọ pe Arẹgbẹṣọla gbọdọ jiya ẹṣẹ ẹ latari pe o gbominira nidii oṣelu.
" Bẹẹ ni Mayor tun sọ pe ko sẹni to le fi buburu san rere, ko lọ ni alaafia".
Abọsẹde tun ṣalaye siwaju ninu atẹjade naa pe ṣe ni wọn tun lo agba oniroyin kan lọjọ kẹrinla, oṣu yii bakan naa torukọ ẹ n jẹ Ebiri Gbọnka nibi to ti sọ nita gbangba pe Arẹgbẹsọla ko gbọdọ lọ lasan, o gbọdọ koju wahala nilẹ Yoruba.
Obinrin naa ni pabanbari ẹ ni eyi to waye niluu Ṣagamu,lakooko ti ẹgbẹ oṣelu ADC fẹẹ ṣe ipolongo fun atundi ibo, ṣugbọn ti wọn ko fun wọn laye tawọn ọlọpaa gbe ẹrọ agbọta min sita, ti wọn si bẹrẹ si nii pariwo le Arẹgbẹṣọla lori nibẹ.
O ni awọn jọ ṣiṣẹ pọ pẹlu akopapọ ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Coalition Oodua Self Determination Group tawọn ti kọkọ fi ilodi wọn han si idunkoko yii.
Wọn ni gẹgẹ bi Dayọ Ogunlana to jẹ alaga wọn ṣe wi, pe ko yẹ ki ilẹ Yoruba gba wọn laaye lati jẹ ki jagidijagan oṣelu waye.
O ni ipa kekere kọ ni Arẹgbẹṣọla ti ko fun idagbasoke ẹgbẹ Oodua fun ki iṣọkan ko waye paapaa nipinlẹ Eko ati Ọṣun.
Ẹgbẹ Ọmọluabi ni ko si ẹsẹ ninu igbesẹ ti Arẹgbẹṣọla gbe lati sọ ara ẹ di ominira nidii oṣelu, to si wa, to si yẹ ki ibọwọ wa fun pẹlu.
Wọn waa lo akoko naa lati kilọ fun gbogbo awọn ti wọn fẹẹ ki wọn maa lo wọn fun idunkoko yii lati jawọ ati pe awọn ko nii la oju wọn silẹ lati ṣe Arẹgbẹṣọla nijamba.
No comments:
Post a Comment