Kọmureedi Abayọmi Sanyaolu, alaga fẹgbẹ apapọ oloṣelu nipinlẹ Ogun, ti mu da awọn araalu loju pe laipẹ yii lawọn yoo gbe abajade ati igbesẹ to ba yẹ lori atundi ibo aṣoju-ṣofin to waye lọjọ Abamẹta, Satide to kọja ni ẹkun Rẹmọ.
Gẹgẹ bi atẹjade ti ẹni to tun jẹ alaga fẹgbẹ oṣelu Action Alliance nipinlẹ Ogun fi sita lo ti ṣalaye pe awọn ti n ṣe akojọpọ gbogbo bi nnkan ṣe lọ si lakooko ibo ọhun Bẹẹ lawọn tun ṣagbeyẹwo ọlọkan-ọ-jọkan lee lori, tawọn o si fẹẹ figba kan bọkan ninu.
O waa mu dawọn araalu atawọn oloṣelu loju pe gbogbo bi nnkan ba ṣe lọ lawọn yoo tan imọlẹ si ati pe bi awọn araalu yoo ṣe gbadun ijọba tiwa-n-tiwa, ti alaafia yoo jọba lo jẹ wọn logun
No comments:
Post a Comment