- O ni akọni meji lọọ lọjọ kan naa.
Ninu atẹjade ti oludasilẹ ẹgbẹ kan ti wọn pe ni 'The Alternative' fi sita lalẹ ana Sannde, lẹyin ti wọn kede ipapoda awọn mejeeji ọhun lo ti sọ pe ipa tawọn mejeeji ti ko nigba ti wọn wa laye ko nii gbagbe ninu itan orileede yii.
O fikun ọrọ ẹ pe Aarẹ tẹlẹ ọhun, Buhari jẹ akikanju oloogun ti ko gba iwa ibajẹ laaye,ko to tiẹ bọ aṣọ oogun silẹ di aarẹ alagbada.
Ṣẹgun Ṣowunmi tun ṣalaye pe oun ti gbọ nipa ọkunrin naa tipẹ ko to digba toun fi mọ ọn.O nipa manigbagbe lo ko nigba to fi ni kawọn Matasine le awọn fe awọn to nda wahala silẹ lati ilẹ Chad kuro lẹnu ala ilẹ wa.
Bẹẹ lo ni ko sẹni to le gbagbẹ gẹgẹ bi ẹni ti ko gba igbakugba laaye nigba to fi apaṣẹ ati gomina lapa ilẹ Hausa.
Ṣẹgun Ṣowunmi tun sọ pe oun ko le gbagbe nigba Buhari fi kọkọ jẹ aarẹ ologun lorileede yii toun wa nileewe girama ologun ti wọn pe ni 'Command Secondary School ni Kaduna', igba naa lo da igbogun tiwa bajẹ silẹ, iṣẹlẹ manigbagbe kan tiẹ waye to mu wọn da igbogun ti awọn obinrin silẹ nileewe ngba naa.
Bẹẹ lo sọ pe gẹgẹ bi aarẹ, oun ti wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, ti Buhari fi bẹrẹ irinajo ẹ lati di adari,nigba naa oun woo bi alatako oloṣelu, o jẹ ẹni toun bọwọ fun un, amọ ko fẹran oun tọrọ ba di ariyanjiyan.
Bakan naa lo tun mẹnuba bi Buhari ṣe fi ọpọlọ ti Ọlọrun fun un yanju wahala to waye lakooko 'Endsars' atawọn nnkan ribiribi to ti ṣe to ti wa nnu akọọlẹ.
Bẹẹ naa ni Ṣowumi tun ṣapejuwe Ọba Sikiru Adetọna, gẹgẹ bi opo nla to di Ijẹbu ati ilẹ Yoruba mu ko to di pe o waja.
O ni gbogbo igba to fi wa laye lo fi sin awọn eeyan ilẹ Ilẹ Ijẹbu lapapọ to si mu idagbasoke ba wọn.
Agba oṣelu PDP tun ṣalaye Ọba Sikiru Adetọna tun jẹ ẹnikan to fi gbogbo aye ẹ ja fun ẹtọ awọn eeyan ẹ nilẹ Ijẹbu.
O ni ṣe ti igbooro nla to mu ba ayẹyẹ ojude ọba ti wọn maa n ṣe nijẹbu ode ni ki a sọ ni abi bi ki i ṣe fẹẹ kawọn eeyan ẹ lọ sẹyin, ti wọn si maa n dide iranwọ si ara wọn.
Ṣowunmi ni o yẹ kawọn ọmọ ilẹ Ijẹbu lọkunrin ati lobinrin maa dupẹ lọwọ Ọba Adetọna fawọn nnkan manigbagbe to ṣe fun wọn.
O waa pari ọrọ ẹ pe ki Ọlọrun fọrukẹ awọn mejeeji ọhun, ko si tun awọn ẹb wọn ati orileede yii ninu.
No comments:
Post a Comment