- BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 4 July 2025

Ko si eso rere tawọn to lọọ darapọ mọ ADC fẹẹ mu jade- Ṣowunmi

Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, to jẹ ọkan lara alẹnulọrọ, ogbontarigi ninu ẹgbẹ oṣrlu PDP lorileede yii ti sọ pe ko si eso rere tawọn to ṣẹṣẹ lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ADC fẹẹ mu jade ati pe awọn oniwabajẹ lo ko ara wọn pọ.

O sọrọ yii nibi apero nla ẹgbẹ kan to da silè iyen Alterntive Movement ṣe niluu Abẹokuta o sọ pe ọrọ ẹgan kọ,ki i ṣe ifẹ ọmọniyn lo gbe wọn debẹ bikoṣe ifẹ ara wọn

Ọtunba Ṣowunmi sọ loju ogunlọgọ awọn eeyan ti wọn wa nibi ayẹyẹ ọhun pe awọnti wọn ko ara wọn jọ ti wọn jọ wọnu ADC,ko ni nnkan ti wọn le fi gbajjọba lọwọ Tinubu ninu ibo to n bọ lọdun 2027, ati pe bigba ti wọn fi akoko wọn ṣofo ni.

O tẹsiwaju ninu ọrọ ẹ pe awọn araalu gan sn ko ni fun wọn laaye, nitori wọn ti kọja ẹni tawọn oloṣelu yoo maa da kaakiri.

O sọ pe awọn araalu ko le gbsgbe pe nnkan ti apa oke ọya ba fi ṣe ọdun mẹjọ, awọn apa to wa nibi nsa yoo ṣọdun mẹjọ wọn pe.

O ni bawo ni wọn ṣe fẹẹ ṣe ti ADG ti Mark jẹ alaga tuntun ti Arẹgbṣọla si jẹ akọwe ṣe fẹẹ ṣe ti wọn yoo fi gbajọba lọwọ Tinubu, ko ti ye oun.
  
Ṣowunmi so pe nnkan ti orileede yii n fẹ lakooko taa wa ni atunṣe lori ibo ati bi wọn yoo ṣe maa yan aṣaaju nidii oṣelu.

O ni iṣẹ oloṣelu ni lati ṣe nnkan to fẹẹ ṣe amọ ti araalu ni lati wo wọn ki wọn si sọ fun wọn pe wọn ti ṣe iru nnkan yii ni aimọye igba.

Ṣowunmi ni pataki iṣẹ to wa niwaju Alternative ni lati maa gba awọn araalu nimọran lọna lati mu ilọsiwaju ba oṣelu nilẹ wa Nijiria.

Ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ Alternstive kaakiri otileede yii lo wa nibi eto ọhun atawọn olori oloṣelu  nipinlẹ Ogun.  

No comments:

Post a Comment

Pages