Ijọba Ogun fawọn agbẹ ni ẹrọ ti yoo maa mu omi jade lakooko ọgbin - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 25 July 2025

Ijọba Ogun fawọn agbẹ ni ẹrọ ti yoo maa mu omi jade lakooko ọgbin




Ijọba ipinlẹ Ogun labẹ ileeṣẹ to n ri si akanṣe ba ayipada ọrọ aje tun ti gbe igbesẹ nla mii-in bawọn agbẹ nipasẹ pipese ẹrọ ti yoo maa mu omi jade wa looorekoore atawọn ohun elomii ti yoo wulo fẹgbẹ awọn agbẹ bii ọgọrun-un.

Eyi to si jẹ lara erongba wọn lati ṣatilẹyin fun  idagbasoke eto ọgbin ati ipese ounjẹ jantiẹrẹ fawọn araalu.

Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ ifilọlẹ pipese ẹrọ naa fawọn to n janfaani ẹ, eyi to waye ni ọfiisi wọn iyẹn OGSTEP, Oke Ilewo niluu Abẹokuta laaarin ọsẹ taa lo tan yii, Kọmiṣanna  feto ọgbin ati aabo fun ounjẹ, Ọnarebu Bolu Owotọmọ, lawọn ṣagbekalẹ iranwọ yii fawọn ẹkun mẹrẹẹrin fọrọ ọgbin nipinlẹ Ogun.

O fikun ọrọ ẹ pe igbesẹ yii yoo tun jẹ ki awon ohun ọgbin tubọ pọ si, ti oun jẹ yoo si pọ si yanturu nipinlẹ Ogun paapaa julọ lorile ede wa.

Bẹẹ lo sọ pe ko to to akoko yii ipinlẹ Ogun, ti da si ọrọ awọn agbẹ nibi tawọn ẹgbẹrun lọna ogoji ti janfaani, to si jẹ pe awọn bii ẹgbẹrun lọna ọgọjọ ni wọn ti forukọsilẹ labẹ ileeṣẹ to n ri si isakoso awọn agbẹ.

Bakan naa ni kọmiṣanna waa rọ awọn agbẹ lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba,ki wọn si lo ẹrọ amomijade tileeṣe OGSTEP fun wọn yii lọna ẹtọ, bẹẹ lo rọ wọn lati tan imọlẹ anfaani ni sọdọ awọn agbẹ ti wọn ko ti ri,ki wọn si tan imọ ati oye ẹ fun wọn pẹlu.

Ninu ọrọ akọwe agba nileeṣẹ naa, Arabinrin Kehinde Jokotoye, o fi idunnu ẹ lori eto to waye naa,o ni gbogbo iṣẹ akanṣe tijọba n ṣe lo mu ipa rere bawọn araalu.

O waa fi akoko naa rọ awọn agbẹ lati rii pe wọn ṣiṣẹ takuntakun ki ounjẹ pọ, ki ayipada rere le de, ki adinku le ba ọwọngogo.

Arabinrin Mosunmọla Owo-Odusi, to jẹ alakoso akanṣe OGSTEP, o sọ pe gbogbo igba nijọba ipinlẹ Ogun ni lọkan lati gbe iṣẹ ọgbin soke ati pe ileeṣẹ wọn yii ni wọn lo lati fi ṣatilẹyin fawọn agbẹ.

Nigba ti wọn sọrọ lorukọ awọn yooku ti wọn jẹ anfaani, Ọmọọba Usman Adekanbi lati Ipokia ati Arabinrin Tosin Ogunkọla lati Ijẹbu Ode fi ẹmi imoore wọn han si ijọba ipinlẹ Ogun ati OGSTEP, fun nnkan ti wọn ṣe yii pẹlu ileri pe wọn yoo lo lọna to tọ.

No comments:

Post a Comment

Pages