-Bẹẹ ni wọn tun ro awọn agbẹ lagbara
Ẹgbẹ kan to nii ṣe pẹlu ilanilọyẹ oṣelu, The Alternative, ni wọn tun ti tẹsiwaju nipa itansimọlẹ lori ọrọ oṣelu nigba ti wọn gbe ipolongo wọn to tako rira tabi tita ibo fawọn araalu lakooko ti idibo ba n waye.
Lọjọruu, ọsẹ yii ni wọn lọ si Ogun West, nibi ti wọn ti kọkọ ṣeto ironilagbara fawọn agbẹ iyẹn awọn ti wọn n pe ni Agbẹ gbelu Agro Network, nibi ti wọn ti fun wọn lawọn eronja to le wulo fun iṣẹ agbẹ wọn.
Ninu ọrọ Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, to jẹ alakoso Alternative, eyi ti Adai Edwin, jẹ lorukọ ẹ lo ti sọ pe iṣẹ ti bẹrẹ ni pẹrẹu bayii lati bẹrẹ si nii la awọn araalu lọyẹ lori eto oṣelu tawọn si rii pe awọn ileto lo yẹ ki wọn ti gbe igbesẹ.
O sọ pe lara erongba ẹgbẹ ọhun ni lati maa ro awọn araalu lagbara ni eyi ti yoo jẹ ki wọn maa yan aṣaaju wọn lainifoya.
O fi kun ọrọ ẹ pe asiko ti to bayii lati tẹ mọ wọn leti pe asiko ti wọn fowo ra ibo tabi ṣe oṣelu ẹtanu ti kọja kaka bẹẹ ẹgbẹ naa ti ṣetan lati ṣagbega aṣa ilanilọyẹ oṣelu ba orileede Naijiria.
Ṣowunmi tun fi kun ọrọ ẹ pe ohun tawọn fẹẹ kọkọ ṣe ni lati jẹ kawọn to wa ni igberiko ati ileto ji ẹri ọkan wọn pepe, ki wọn mu ọkan kuro ninu a n ra ibo, tabi ṣeleri tawọn oloṣelu n ṣe lakooko ipolongo ṣugbọn ti wọn ko nii muṣẹ.
O ni oun fẹẹ ki wọn mọ pe igba naa ti kọja lọ, o si ti di ohun igbagbe ninu itan oṣelu wa. O ni ẹgbẹ Alternative ti ṣetan lati ji wọn eeyan kuro ninu oorun ikoro yii.
O ni erongba awọn ni lati rii pe lskooko ibo,awọn araalu yoo le fa oludije ti wọn fọkantan silẹ lati ṣoju wọn.
Bẹẹ lo ni awọn tun fẹẹ kawọn ara igberiko mọ pe akoko idibo bayii kọja eyi ti wọn fọwọ yẹpẹrẹ mu, o ni awọn eeyan ko le pọ to bayii, ko dọjọ ibo ki wọn ma le jade wa ṣe ojuṣe wọn.
O ni bi wọn ba ṣe jade sii lati dibo ni yoo tọka si bi ẹni ti wọn fẹ ko ṣoju wọn yoo ṣe wọle.
Ninu ọrọ Ẹni ọwọ Oluṣọla Ṣalau, to jẹ alaga ẹgbẹ naa lapa ilẹ Yoruba, o mu dawọn agbẹ atawọn to wa nibi eto naa loju pe wọn yoo maa ri atilẹyin wọn.
O ni eto n lọ lọwọ lati tun ro awọn agbẹ ni tirakitọ atawọn ohun elo mii ti yoo jẹ ki iṣẹ wọn tẹsiwaju.
Lọjọ naa ni Alternative Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi fi awọn bii ajẹlẹ iyẹn fantalisa atwọn mii in fawọn agbẹ.
No comments:
Post a Comment