Ṣẹgun Ṣowunmi gba Sanwo-Olu lamọran lati tubọ ṣatunṣe ayika ipinlẹ Eko - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday, 25 June 2025

Ṣẹgun Ṣowunmi gba Sanwo-Olu lamọran lati tubọ ṣatunṣe ayika ipinlẹ Eko





Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, to jẹ alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lorileede yii ti gba Gomina Babajide Sanwo-Olu lamọran lati tubọ ṣafikun erongba ẹ lati tun ayika ipinlẹ Ogun ṣe.

Ninu atẹjade ti oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun lọdun 2023, fi sita lati fi ki Gomina Sanwo-Olu ku ayẹyẹ ọjọọbi ọgọta ọdun lori eepẹ lo ti kan sara si gẹgẹ bi akọni fawọn iṣẹ akanṣe to ti ṣe latigba to ti dori ipo.

Ṣowunmi tun fi kun pe ọrọ ẹ pe ki Gomina Sanwo-Olu fun ṣokoto ẹ ko le daadaal ati  rii pe saa to ku fun gẹgẹ bi gomina nipinlẹ Eko, o fi kọjumọ eto ayika fawọn ibi to ni atunṣe lee lori.

O tẹsiwaju ninu ọrọ ẹ pe" Mo ki ọ ku oriire ọjọọbi ọgọta ọdun, ko buru ju rara fawọn aṣeyọri ti ko ṣee mẹnuba fun irinajo naa.

"Ṣugbọn ni bayii, akoko ti to lati ṣiṣẹ pọ, ki ẹni ti yoo ba gbapo gomina lọjọ iwaju yoo tun fẹẹ sọ pe oun tọrọ aforiji lati tun kọ awọn ile igbalode".

O wa lo anfaani naa lati pe Tokunbọ Wahab to jẹ kọmiṣanna fọrọ iṣẹ ati alumọni omi nipinlẹ Eko,lati mu erongb ẹ ṣẹ kswọn iṣẹ tijọba Sanwo-Olu n ṣe ko le pari lakooko.

Ṣowunmi waa pe Sanwo-Olu nija lati bọ sita ko wa sọ nipa ibi ti eto ayika de, awọn ibi to ba yẹ ko bu ṣubu, ko tete ṣe lakooko ati ibi to yẹ ki atunṣe wa,ko ṣe e.

Bẹẹ lo tọpaṣẹ ibi ti idagbasoke ti bẹrẹ, nibẹ lo ti gboriyin fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, Babatunde Faṣọla, Akinwunmi Ambọde ti wọn ti jẹ gomina ri nipinlẹ Eko fawọn iṣẹ ribiribi ti wọn ti ṣe.

O waa pari ọrọ ẹ pe ipinlẹ Eko, ki i ṣe ti baba ẹni kan,ṣugbọn o jẹ ilẹ fawọn ti wọn fẹẹ ki ọrọ aje wọn gun rege, ki ilọsiwaju si maa tẹsiwaju.

No comments:

Post a Comment

Pages