Ipinlẹ Ogun yoo gboro mọ awọn to n ṣe fayawọ ogun oloro-Ọtunla Ọga agba fajọ ẹṣọ aṣọbọde nipinlẹ Ogun, Godwin Ọtunla, ti sọ pe awọn ti ṣetan lati jẹ ki ipinlẹ ọhun gbona mọ awọn to n ṣe fayawọ ogun oloro wọlu. Ọ ṣọrọ yii lakooko to n jiṣẹ irinju ẹ fawọn oniroyin to si tun lo anfaani naa lati gbe awọn ogun oloro ti wọn ri gba fun ileeṣẹ to n gbogun ti ogun oloro iyẹn NDLEA. O fikun ọrọ ẹ pe owo tawọn pa wọle tun ti fi miliọnu mẹwaa ati ẹgbẹrun lọna ẹẹgbẹta naira iyẹn ninu oṣu karun-un ju miliọnu mejilelogoji, ti wọn pa ninu oṣu kẹrin to gbaṣẹ. Ọtunla sọ pe ohun to jẹ kawọn ṣe aṣeyọri yii da lori bi wọn ṣe ja fafa lori iṣẹ ti wọn yan laayo yii, ti wọn ko si mẹhẹ nidi ẹ rara. O ṣalaye siwaju si pe gbogbo ọna lawọn n gba lati fi doju ija kọ awọn ti wọn n wa ifasẹyin ba ọrọ aje wa lorileede yii nipasẹ fayawọ. Lara awọn nnkan to ṣafihan pe wọn ri gba lọwọ awọn fayawọ yii ni apo igbo to le ni ẹgbẹrun lọna kan abọ, ọta ibọn loriṣirisi ati ike epo pupa. Nigba to n tẹwọ gba awọn ogun oloro naa, ọga agba fun ajọ NDLEA,lagbegbe naa Ẹkundayọ Williams dupẹ lọwọ ọga aṣọbode ọhun fun ọna to n gba lati gbogun tawọn onifayawọ. O sọ pe ohun to jẹ ki aṣeyọri waye ko ju ifọwọsowọpọ to wa laaarin ileeṣẹ mejeeji, o ni bi NDLEA ko ba mu wọn, awọn aṣọbode naa yoo rawọ to wọn. O wa rọ awọn aṣọbọde lati ma ṣe rẹwẹsi lori akintiyan wọn lati gbogun ti ogun oloro. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 19 June 2025

Ipinlẹ Ogun yoo gboro mọ awọn to n ṣe fayawọ ogun oloro-Ọtunla Ọga agba fajọ ẹṣọ aṣọbọde nipinlẹ Ogun, Godwin Ọtunla, ti sọ pe awọn ti ṣetan lati jẹ ki ipinlẹ ọhun gbona mọ awọn to n ṣe fayawọ ogun oloro wọlu. Ọ ṣọrọ yii lakooko to n jiṣẹ irinju ẹ fawọn oniroyin to si tun lo anfaani naa lati gbe awọn ogun oloro ti wọn ri gba fun ileeṣẹ to n gbogun ti ogun oloro iyẹn NDLEA. O fikun ọrọ ẹ pe owo tawọn pa wọle tun ti fi miliọnu mẹwaa ati ẹgbẹrun lọna ẹẹgbẹta naira iyẹn ninu oṣu karun-un ju miliọnu mejilelogoji, ti wọn pa ninu oṣu kẹrin to gbaṣẹ. Ọtunla sọ pe ohun to jẹ kawọn ṣe aṣeyọri yii da lori bi wọn ṣe ja fafa lori iṣẹ ti wọn yan laayo yii, ti wọn ko si mẹhẹ nidi ẹ rara. O ṣalaye siwaju si pe gbogbo ọna lawọn n gba lati fi doju ija kọ awọn ti wọn n wa ifasẹyin ba ọrọ aje wa lorileede yii nipasẹ fayawọ. Lara awọn nnkan to ṣafihan pe wọn ri gba lọwọ awọn fayawọ yii ni apo igbo to le ni ẹgbẹrun lọna kan abọ, ọta ibọn loriṣirisi ati ike epo pupa. Nigba to n tẹwọ gba awọn ogun oloro naa, ọga agba fun ajọ NDLEA,lagbegbe naa Ẹkundayọ Williams dupẹ lọwọ ọga aṣọbode ọhun fun ọna to n gba lati gbogun tawọn onifayawọ. O sọ pe ohun to jẹ ki aṣeyọri waye ko ju ifọwọsowọpọ to wa laaarin ileeṣẹ mejeeji, o ni bi NDLEA ko ba mu wọn, awọn aṣọbode naa yoo rawọ to wọn. O wa rọ awọn aṣọbọde lati ma ṣe rẹwẹsi lori akintiyan wọn lati gbogun ti ogun oloro.



Ọga agba fajọ ẹṣọ aṣọbọde nipinlẹ Ogun, Godwin Ọtunla, ti sọ pe awọn ti ṣetan lati jẹ ki ipinlẹ ọhun gbona mọ awọn to n ṣe fayawọ ogun oloro wọlu.

Ọ ṣọrọ yii lakooko to n jiṣẹ irinju ẹ fawọn oniroyin to si tun lo anfaani naa lati gbe awọn ogun oloro ti wọn ri gba fun ileeṣẹ to n gbogun ti ogun oloro iyẹn NDLEA.

O fikun ọrọ ẹ pe owo tawọn pa wọle tun ti fi miliọnu mẹwaa ati ẹgbẹrun lọna ẹẹgbẹta naira iyẹn ninu oṣu karun-un ju miliọnu mejilelogoji, ti wọn pa ninu oṣu kẹrin to gbaṣẹ.

Ọtunla sọ pe ohun to jẹ kawọn ṣe aṣeyọri yii da lori bi wọn ṣe ja fafa lori iṣẹ ti wọn yan laayo yii, ti wọn ko si mẹhẹ nidi ẹ rara.

O ṣalaye siwaju si pe gbogbo ọna lawọn n gba lati fi doju ija kọ awọn ti wọn n wa ifasẹyin ba ọrọ aje wa lorileede yii nipasẹ fayawọ.

Lara awọn nnkan to ṣafihan pe wọn ri gba lọwọ awọn fayawọ yii ni apo igbo to le ni ẹgbẹrun lọna kan abọ, ọta ibọn loriṣirisi ati ike epo pupa.

Nigba to n tẹwọ gba awọn ogun oloro naa, ọga agba fun ajọ NDLEA,lagbegbe naa Ẹkundayọ Williams dupẹ lọwọ ọga aṣọbode ọhun fun ọna to n gba lati gbogun tawọn onifayawọ.

O sọ pe ohun to jẹ ki aṣeyọri waye ko ju ifọwọsowọpọ to wa laaarin ileeṣẹ mejeeji, o ni bi NDLEA ko ba mu wọn, awọn aṣọbode naa yoo rawọ to wọn.

O wa rọ awọn aṣọbọde lati ma ṣe rẹwẹsi lori akintiyan wọn lati gbogun ti ogun oloro.


No comments:

Post a Comment

Pages