Ọkan lara agbegbe ti wọn kii saaba fojusi nipinlẹ Eko ni Makoko, ohun lo wa di ibudo ifilọlẹ sitoofu ti kii yọ eefin tijọba gbe kalẹ fun idile kọọkan lati ṣe afọmọ ayipada oju ọjọ.
Igbesẹ yii wa ni ibamu pẹlu erongba ijọba lati pin adogan idana ti kii ṣeefin tiye rẹ jẹ ọgọrin miliọnu fawọn idile kọọkan kaakiri orileede Naijiria eyi ti wọn ṣafihan rẹ lawọn agbegbe to sun mọ eti omi.
Ki imọtoto le tẹsiwaju lawọn agbegbe kọọkan atipe adogan igbalode naa yoo rọpo ṣiṣẹ amulo igi ti eefin rẹ le ṣakoba fun ilera. Ida mẹwaa lo maa kan ipinlẹ Eko, ninu sitoofu ti kii ṣeefin naa leyi to jasi pe, sitoofu miliọnu mẹjọ nijọba Eko fẹẹ pin fawọn eeyan agbegbe ijọba ibilẹ ati ijọba ibilẹ onidagbasoke mẹtadinlọgọta.
Nigba to n sọrọ nibi ifilọlẹ naa lọjọru Wẹside, ọṣẹ yii, Oludamọran Agba si Gomina Babajide Sanwo-Olu lori ayipada oju ọjọ ati ọrọ aje, Titilayọ Oshodi, tọka idi pataki ti Makoko ṣe jẹ afojusun ijọba tawọn si ma bẹrẹ pinpin ida akọkọ sitoofu naa ni ọgbọnjọ oṣu kẹfa, ọdun 2025.
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ " Makoko lo kọkọ ma jẹ anfaani iṣẹ akanṣe yii bakan naa la tun dupẹ lọwọ awọn olugbe Makoko fun bi wọn ṣe gba wa tijo tayọ, eyi jasi pe,awọn ni ida akọọkọ to jẹ anfaani adogan idana ti kii ṣeefin yii, awọn naa ni wọn kọkọ ni iriri nipa iṣẹ adogan naa kaakirii orileede Naijiria".
Oshodi ṣalaye siwaju si i pe, eto naa ti wa nilẹ latọdun to kọja tiwọn si ti firoyin naa sita bakan naa ni wọn ṣafihan sitoofu idana naa tiwọn si ṣapejuwe iwulo rẹ.
Sitoofu idana naa, gẹgẹ bi Oshodi ṣe ṣalaye , ni iwulo loriṣiriṣi: “ Kii ṣeefin, ko pa ilera lara, o nii ṣe pẹlu idagbasoke ọrọ aje bakan naa lo n mu ayipada rere ba oju ọjọ .”
O ni, gomina Babajide Sanwo-Olu pẹlu ifẹ to ni sawọn olugbe Eko ti pinnu lati ṣe ohun to jọju. O sami ayẹyẹ ọjọọbi ọgọta ọdun pẹlu ṣiṣe ohun ara ọtọ fawọn awọn agbegbe bii Makoko, nibiti ayipada to fojuhan ti bẹrẹ.
Adari agba kan ni ileeṣẹ Greenplinth Africa, Yahya Ahmed, to tun jẹ alakooso eto naa, ṣatẹnumọ ipa ti iṣẹ akanṣe naa ni lori idaabobo ayiika ati ironilagbara.
“ A fojusun Makoko nitoripe o jẹ ibi ti wọn ti n lo ina igi julọ l'Ekoo atipe sitoofu tijọba ṣafihan rẹ ko le ṣakoba fun ilera eyi to jẹ ko wulo fun gbogbo idile, kii ṣeefin bẹẹni kii fa ikọ.
.
Ọkan lara awọn olugbe Apollo, agbegbe kan ni Makoko, Abilekọ Bidemi, jẹrii pe sitoofu naa dara atipe o maa ni alopẹ.
Awọn gbajumọ olorin tiwọn wa nibẹ lọjọ naa ni, Daddy Showkey,Alariwo ati oṣere tiata nni, Folukẹ Daramọla ti wọn si kede atilẹyin wọn fun igbesẹ naa.
Lakotan, Baale Makoko, Orioye Jephter Ogungbure, aṣoju agbegbe Yaba CDC, Aṣiwaju Yusuf;aṣoju Iyalọja Makoko, ni wọn fi idunnu wọn han si igbesẹ naa pẹlu
adura fawọn tiwọn ṣe atọna iṣẹ akanṣe naa wa si agbegbe Makoko.
No comments:
Post a Comment